Àwọn Ìṣé ÌrònúpìwàdàÀpẹrẹ

Acts of Repentance

Ọjọ́ 5 nínú 5

Ọlọ́run rán ọmọ Rẹ̀ kan ṣoṣo wá sí ayé fún ìdí pàtàkì: láti fún wa ní ìyè titun. Ní Lúùkù 5:27-32, Jésù ṣe ìtúpalẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ báyìí: "Kìí ṣe àwọn tó ní ìlera pípé ló nílò dókítà, bí kò ṣe àwọn tó ń ṣàárẹ̀. N kò wá láti pé àwon olódodo, bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sí ìrònúpìwàdà." Kristi wá sọ́dọ̀ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bí èmí àti ìwọ kí a lè ní ìgbé ayé titun nípasẹ̀ ìrònúpìwàdà. A ti jogún iṣẹ́ ìránṣẹ́ Kristi. Ìpè wa kìíṣe láti jẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn olódodo bíkòṣe sí àwọn tó ti nù tó sì nílò ìdàríji. Tí o bá tí ṣe ìrònúpìwàdà ní tòótọ́ tí Ọlọ́run sì ti dárí ìkùnà jì ọ́, èyí mú pọn dandan fún ọ láti jíhìn náà fún gbogbo ènìyàn tó nílò ìrònúpìwàdà. Ìyípadà ayé tìrẹ lè mú ìrònúpìwàdà bá ayé ẹlòmíràn. Ta ni o lérò wípé ó nílò ìrònúpìwàdà àti ìdàríji Ọlọ́run? Báwo ní ìtàn bí Ọlọ́run ti dárí jì ọ́ ti lè ran enìkan lọ́wọ́ láti wá sí ironuwapada?

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Acts of Repentance

Ìrònúpìwàdà jẹ́ ọ̀kan lára ìgbésẹ̀ tó ṣe kókó tí à ń gbé láti mọ Krístì ní Olùgbàlà wa. Ìrònúpìwàdà ni ojúṣe wa, Ìdáríjì sì ni èsì Ọlọ́run sí wa láti inú ìfẹ́ pípé tí ó ní sí wa. Lásìkò ètò ọlọ́jọ́ márùún yìí, wàá gba bíbélì kíkà ojojúmọ́ àti àmúlò ní ṣókí tí a gbékalẹ̀ láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ní òye síi nípa ìwúlò Ìrònúpìwàdà nínú ìrìn wa pẹ̀lú Krístì. Fún àwọn ètò míràn, ṣe àyẹ̀wò www.finds.life.church

More

We would like to thank Life.Church for providing this plan. For more information, please visit: www.life.church