Àwọn Ìṣé ÌrònúpìwàdàÀpẹrẹ

Acts of Repentance

Ọjọ́ 3 nínú 5

Ìrònúpìwàdà ni atọkùn fún ìdáríjì. Bí a bá ronú pìwàdà Ọlọ́run á dáríjì. Ìrònúpìwàdà àti ìdáríjì kìí ṣe àgbékalẹ̀ tí ó rújú. Ìrònúpìwàdà ni ìgbésẹ̀ tí àwá gbé nígbà tí ìdáríjì jẹ́ ìṣesí Ọlọ́run sí wa nítorí ìfẹ́ àìlábàwọ́n tí ó ní fún wa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlànà yìí rọrùn, agbára ìdáríjì Ọlọ́run kò ṣeé dá iye lé. Ìdáríjì Ọlọ́run ń pa òkùnkùn rẹ́ nínú ayé wa ó sì ń mú wa wá sínú ìmọ́lẹ̀ láì ka ẹṣẹ̀ tí a dá kún. Ìdáríjì Ọlọ́run bo GBOGBO ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀ àti tìrẹ náà. Ipa wo ni agbára ìràpadà tí ó ti inú ìdáríjì Ọlọ́run wá kó nínú ayé rẹ, báwo ló sì ṣe yí ayé rẹ padà?

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Acts of Repentance

Ìrònúpìwàdà jẹ́ ọ̀kan lára ìgbésẹ̀ tó ṣe kókó tí à ń gbé láti mọ Krístì ní Olùgbàlà wa. Ìrònúpìwàdà ni ojúṣe wa, Ìdáríjì sì ni èsì Ọlọ́run sí wa láti inú ìfẹ́ pípé tí ó ní sí wa. Lásìkò ètò ọlọ́jọ́ márùún yìí, wàá gba bíbélì kíkà ojojúmọ́ àti àmúlò ní ṣókí tí a gbékalẹ̀ láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ní òye síi nípa ìwúlò Ìrònúpìwàdà nínú ìrìn wa pẹ̀lú Krístì. Fún àwọn ètò míràn, ṣe àyẹ̀wò www.finds.life.church

More

We would like to thank Life.Church for providing this plan. For more information, please visit: www.life.church