Àwọn Ìṣé ÌrònúpìwàdàÀpẹrẹ

Acts of Repentance

Ọjọ́ 4 nínú 5

Ǹjẹ́ o ti sọnù rí? Ọ̀kan nínú àwọn ǹkan tó pinni l'ẹ́mìí jùlọ ní kí ènìyàn má mọ ibi tí ó nlọ. Èyi tilẹ̀ máa ńkó jìnìjìnì bo'ni nígbà míràn. Ní ẹsẹ 25 Pétérù fi wá wé àgùntàn nípa pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá, a ti fìgbà kan ṣìnà rí tí a sì ṣáko lọ. A ò mọ ibi tí ó yẹ kí a lọ, àmọ́ lẹ́yìn tí a ronúpìwàdà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wa, tí a sì ti rí ìdáríjì gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, a ti padà sínú agbo tí Ọlórun ńdarí bíi Olùṣọ́àgùntàn. Níbo ni o ti máa ń sábà tasẹ̀-àgẹ̀rẹ̀? Bóyá ò ńtiraka láti dúró lójú ọ̀nà Ọlọ́run, ṣùgbọ́n tí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ínú ayé rẹ ńgbá ọ ṣí òpópó-ònà tí kò yẹ. Ṣe ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ náà fún Ọlọrun. Ronúpìwàdà kúrò nínú rẹ̀ lónìí, kí o sì bèrè fún ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run láti lè borí rẹ̀ pátápátá.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

Acts of Repentance

Ìrònúpìwàdà jẹ́ ọ̀kan lára ìgbésẹ̀ tó ṣe kókó tí à ń gbé láti mọ Krístì ní Olùgbàlà wa. Ìrònúpìwàdà ni ojúṣe wa, Ìdáríjì sì ni èsì Ọlọ́run sí wa láti inú ìfẹ́ pípé tí ó ní sí wa. Lásìkò ètò ọlọ́jọ́ márùún yìí, wàá gba bíbélì kíkà ojojúmọ́ àti àmúlò ní ṣókí tí a gbékalẹ̀ láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ní òye síi nípa ìwúlò Ìrònúpìwàdà nínú ìrìn wa pẹ̀lú Krístì. Fún àwọn ètò míràn, ṣe àyẹ̀wò www.finds.life.church

More

We would like to thank Life.Church for providing this plan. For more information, please visit: www.life.church