Bí A Ṣe Lè Ka Bíbélì (Àwọn Ìpìlẹ̀)Àpẹrẹ
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Ó Yanrantí Ń Ṣe Àyípadà
Àwọn tí kò kọ̀ kí á pa àwọn lára ń rìn ní àárín ohun ìjìnlẹ̀. – Theodore Roethke
Fi ojú inú wo ara rẹ pé ò ń wọ inú ọ́fììsì dókítà lọ nítorí pé ò ń ṣe àìsàn, ṣùgbọ́n dípò kí wọ́n lo ẹ̀rọ tí a fi ń wọn gbígbóná tàbí títutù nnkan bí ó ti yẹ (nípa fífi sí ẹnu, etí, tàbí iwájú órí rẹ), wọ́n wá fi sí àtẹ́lẹwọ́ rẹ. Lẹ́hìn ìṣẹ́jú díẹ̀, kí nọ́ọ̀sì mú-un kí ó sì sọ fún ọ pé ìwọ̀n òtútù tàbí gbígbóná ara rẹ wà ní déédé.
Kíni èsì tí ìwọ yóò fun? Ó dára nítòótọ́ lójú, ṣùgbọ́n o kò lò ó ní ọ̀nà tí ó yẹ.
Nínú ibẹ̀yẹn, tí a bá lo ẹ̀rọ tí a fi ń mọ tútù tàbí gbígbóná báyìí, kò lè ṣe ju kí ó ṣe ìdiwọ̀n títutù tàbí gbígbóná àyíká tí ó wà. Kìí ṣe pé ẹ̀rọ yìí fúnrarẹ̀ ti bàjẹ́ tàbí pé kíkà rẹ̀ kò pé mọ́, ó kàn jẹ́ pé wọn kò lò ó ní ọ̀nà tí ó yẹ.
Ní ọ̀nà kan náà, ní ìgbà tí a bá pa Bíbélì tì sí ẹ̀gbẹ́ kan à ń pàdánù agbára ìjìnlẹ̀, òtítọ́, àti ìgbésí ayé tí ó ń dúró dè wá pé kí á ṣe àwárí òun. Bíbélì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọ̀nà àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run yàn láti fi ara Rẹ̀ hàn fún wa. Tí a bá fẹ́ láti ní, wà, kí á sì ṣe ohun gbogbo tí Ọlọ́run ti pinnu rẹ̀, gbogbo ṣíṣe bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú sísúnmọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn irin iṣẹ́ àti àwọn èrò tí ó tọ́.
Fún ìrìn àjò Krìstẹ́nì ti èmi, àwọn ọ̀wọ̀n méje tí ó múná d'óko (tí ó sì ń ṣe àyípadà) fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni èyí:
- Níní òye àwọn ohun tí ó yí ibi kíkà ká.
- Fífi àṣà lélẹ̀.
- Ṣíṣe àmúlò àkọ́sórí.
- Lílo àwọn ohun èlò tí ó tọ́.
- Dída ara pọ̀ mọ́ àwọn ẹlòmíràn láti kọ́ ẹ̀kọ́.
- Fífi àdúrà kún-un.
- Sísa ipá láti nà tán.
Ìrìn tìrẹ lè ní ju àwọn yìí lọ, ṣùgbọ́n dájúdájú kò lè dín ní méje yìí. Wọ́n ti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún mi láti dàgbà ju ohun tí mo rò pé ó ṣeé ṣe lọ, mo sì gbàgbọ́ pé wọ́n lè ṣe bákan náà fún ìwọ náà.
Mo ní ìrètí mo sì gbàdúrà pé kí o ní ìfẹ́ sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú ìtara gbígbóná. Àti ní ìkẹyìn, pé nítòótọ́ yóò di àtùpà sí ẹsẹ̀ rẹ àtí ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà rẹ.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ó rọrùn láti rẹ̀wẹ̀sì, láti rò pé a kò múra tó, tàbí pé a kò ní ìtọ́sọ́nà ní ìgbà tí ó bá kan Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Èrò mi ni láti mú ìlànà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rọrùn fún ọ ní àwọn ọ̀nà díẹ̀ nípa kíkọ́ ọ ní mẹ́ta nínú àwọn ìlànà tí ó ṣe pàtàkì jù lọ láti ṣe àṣeyọrí nínú Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. D'ara pọ̀ mọ́ ètò yìí kí o ṣe àwárí bí o ṣe lè ka Bíbélì, kìí ṣe fún àlàyé nìkan, ṣùgbọ́n fún ìyípadà ìgbésí ayé lónìí!
More