Bí A Ṣe Lè Ka Bíbélì (Àwọn Ìpìlẹ̀)Àpẹrẹ
Ìdí tí kíkọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì ṣe ṣe pàtàkì
Kò ṣe é ṣe kí á mọ Ọlọ́run láì mọ Bíbélì.
Mo rántí ìgbà àkọ́kọ́ tí mo gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí. Mo jẹ́ ọ̀dọ́ Kristẹni tí ó ní ìháragàgà láti yan ohun tí ó tọ́ láti tọ́ ọkàn-àyà mi sọ́nà sí àwọn ìfẹ́-ọkàn títọ́. Mo mọ̀ wípé Ọlọ́run le yí ayé mi padà mo sì fẹ́ mọ̀-Ọ́n tímọ́tímọ́.
Báwo ni ó ṣe rí? Kíni Ó fẹ́ láti ọ̀dọ̀ mi? Kíni ìdí tí mo fi wà níbí?
Ní ọdún mẹwàá síwájú, mo fi sí isẹ́ láti kọ́ Bíbélì bí mo ti lè kọ́ kí n le mọ Ọlọ́run jinlẹ̀. Ìpinnu náà ti mú mi lọ sí ọ̀nà tí èmi kò le rò rárá.
Ìfọkànsìn kúkúrú yìí jẹ́ ìfihàn sí díẹ̀ nínú àwọn òye tí ó wúlò jùlọ tí mo ní ní ọdún mẹwàá tí ó kọjá. Ìwọ yíò ṣe àwárí àwọn ọ̀nà, àwọn irinṣẹ́, àti àwọn ọgbọ́n láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ láti ní ànfààní púpọ̀ jùlọ nínú àkókò kíkà rẹ, bákan náà ìwúrí láti gbàgbọ́ pé mímọ Bíbélì rẹ tọ́ sí gbogbo iṣẹ́ tí o nílò nítorí èrè náà ni Ọlọ́run fúnra Rẹ̀.
Lo ìpèníjà náà kí o sì kọ́ bí o ṣe lè yí ìrírí Bíbélì rẹ padà láti iṣẹ́ lásán sí àṣà tí ó ṣe pàtàkì. Ọlọ́run ń retí rẹ kí o le mọ Òun síi. Ó ti fi ìpè nlá pè ọ́. Ohun tí yíò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn nàá wà lọ́wọ́ rẹ.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ó rọrùn láti rẹ̀wẹ̀sì, láti rò pé a kò múra tó, tàbí pé a kò ní ìtọ́sọ́nà ní ìgbà tí ó bá kan Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Èrò mi ni láti mú ìlànà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rọrùn fún ọ ní àwọn ọ̀nà díẹ̀ nípa kíkọ́ ọ ní mẹ́ta nínú àwọn ìlànà tí ó ṣe pàtàkì jù lọ láti ṣe àṣeyọrí nínú Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. D'ara pọ̀ mọ́ ètò yìí kí o ṣe àwárí bí o ṣe lè ka Bíbélì, kìí ṣe fún àlàyé nìkan, ṣùgbọ́n fún ìyípadà ìgbésí ayé lónìí!
More