Bí A Ṣe Lè Ka Bíbélì (Àwọn Ìpìlẹ̀)Àpẹrẹ

How To Study The Bible (Foundations)

Ọjọ́ 4 nínú 5

Àdúrà Ni Ìbẹ̀rẹ̀ Àti Ìparí Ẹ̀kọ́ Bíbélì Tí ó Múná D'Óko

Ó nira láti jẹ́ Kristẹni tí kìí gbàdúrà bí ó ti nira láti wà láàyè láì mí èémí. – Martin Luther

Ọ̀kan lára àwọn oúnjẹ tí mo fẹ́ràn jù lọ ni adìyẹ sísun tí a ti yí l'áta. Ní ìgbà ẹ̀rùn tí ó kọjá, mo ṣe àwárí nípa bí a ti ń yí oúnjẹ l'áta nítorí mo fẹ́ ní òye ǹkan tí ó ń ṣẹlẹ̀ tí ó fi dùn bẹ́ẹ̀. Ǹkan tí mo bá bọ̀ nìyí.

Ní ìgbà tí o bá yí oúnjẹ l'áta, lọ́pọ̀ ìgbà ẹran bí adìyẹ ni, o máa fi ata náà àti àwọn èròjà míràn (bíi wáìnì kíkan tàbí omi ọsàn-wẹ́wẹ́) pa gbogbo ara rẹ̀. Àwọn èròjà olómi yìí máa mú àwọ̀ ẹran yìí rọ̀, àwọn ata àti èlò tí ó kù sì màa ráàyè wọ inú ẹran náà lọ dáadáa.

Yíyí ẹran l'áta a máa gba àkókò. O kò lè sọ ẹran adìyẹ sínú èròjà fún wákàtí mélòó kan kí o wá lérò wípé ó máa gba àdíndùn àwọn èròjà náà sára. O ní láti fún àwọn èròjà náà ní ààyè láti tòrò.

Àdúrà dà bíi yíyí Kristẹni l'áta. Gbígba àdúrà pẹ̀lú, àti nínú, Bíbélì a máa gbà wá ní ààyè láti jókòó sínú òtítọ́ Ọlọ́run fún ìgbà pípẹ́ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí yóò mú kí gbogbo awọ ọkàn wa tí ó yigbì rọ̀ àti wípé ó máa “mú àdíndùn” wọnú ayé wa tí yóò mú wa ṣe ju bí àwa fúnra wa tilè ṣe lọ.

Ní àfikún, ẹ jẹ́ kí n ṣe àfihàn àdúrà tí mo máa ń gbà ní gbogbo ìgbà tí mo bá gbé Bíbélì mi:

Olúwa, dákun ṣí ọkàn mi payá sí Ọ̀rọ̀ Rẹ, kí o sì ṣí Ọ̀rọ̀ Rẹ payá fún mi.

Èyí máa ń tẹ́ pẹpẹ èrò àti ọkàn mi fún ǹkan gbòógì láti ṣẹlẹ̀ ní àkókò Bíbélì kíkà ojoojúmọ́ mi. Mo fẹ́ ní ìyípadà. Mo fẹ́ kí Ẹ̀mí Mímọ́ tan ìmọ́lẹ́ sí Ọ̀rọ̀ náà. Àwọn ìrètí yìí ni mo ma ń sọ ní ibi àdúrà kúkúrú náà.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà ni o ní láti fi àdúrà sí inú ìṣe tì o bá fẹ́ ka Bíbélì. Ní àkókò yìí, mo rọ̀ ọ́ láti gba àdúrà kúkúrú yìí kí o wá wòye ohun tí yóò yí padà lẹ́yìn rẹ̀.

Ìmọ̀ràn Ńlá: Ṣe àdúrà ti sú ọ nítorí ó dà bíi wípé Ọlọ́run kò gbọ́ tàbí dáhùn? Jẹ́ kí ń fún ọ ní ìmọ̀ràn tí olùṣọ́àgùtàn mi fún mi: gé ọgbẹ́ rẹ kéré. . Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni ó rò wípé gbígbọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run jẹmọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ àgbàyanu, tí ó máa yí ayé ẹni padà. Àmọ́ òtítọ́ ibẹ̀ ni wípé, Ọlọ́run àti Ẹ̀mí Mímọ́ ń bá ọ sọ̀rọ̀ ní ojoojúmọ́ (kódà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan!). Gígé ọgbẹ́ rẹ kéré túmọ̀ sí (1) níní ìrètí wípé Ọlọ́run máa kọ̀ sí ọ àti (2) ṣíṣe àwárí lójú méjèèjì àwọn ọ̀nà kéékèèké tí Ó lè gbà ṣe èyí. O kò nílò ìrírí àgbàyanu bíi ti Mósè kí o tó ní ìbápàdé pẹ̀lú Ọlọ́run; ní ìgbà míràn, orin kan pàtó lórí aṣọ̀rọ̀-mágbèsì tó láti mú irúfẹ́ ìbápàdé yìí wáyé.

Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

How To Study The Bible (Foundations)

Ó rọrùn láti rẹ̀wẹ̀sì, láti rò pé a kò múra tó, tàbí pé a kò ní ìtọ́sọ́nà ní ìgbà tí ó bá kan Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Èrò mi ni láti mú ìlànà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rọrùn fún ọ ní àwọn ọ̀nà díẹ̀ nípa kíkọ́ ọ ní mẹ́ta nínú àwọn ìlànà tí ó ṣe pàtàkì jù lọ láti ṣe àṣeyọrí nínú Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. D'ara pọ̀ mọ́ ètò yìí kí o ṣe àwárí bí o ṣe lè ka Bíbélì, kìí ṣe fún àlàyé nìkan, ṣùgbọ́n fún ìyípadà ìgbésí ayé lónìí!

More

A fẹ́ dúpẹ́ ní ọwọ́ Faithspring fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé sí iwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.fromhispresence.com