Mú Ẹ̀rù Kúrò Lọ́nàÀpẹrẹ
Njẹ́ o ti wọ ọkọ̀ òfurufú rí, pàápàá èyí tó ń fò nínú ìjì? Ní irú àkókò yí, ó máa dàbí wípé ọkọ̀ náà fẹ́ dànù nígbà míràn, èyí tó lè mú kí àyà rẹ já díẹ̀. Tí o bá ti de okùn ìdáàbòbò rẹ tẹ́lẹ̀, ó ṣeé ṣe kí o tún un ṣán lẹ́ẹ̀kansi. Nítorí wípé òfurufú ni ẹ ti ń fò, ọkàn rẹ lè má fi taratara balẹ̀. Bóyá ìlà kan náà lò ń tún kà ṣá nínú ìwé ọwọ́ rẹ, nítorí ìjì tó kọlu ọkọ̀ òfurufú yìí tí fa ìpòrúru sí ọ lọ́kàn.
Kò ní yani lẹ́nu tí atukọ̀ bá kéde wípé: “Ọkọ̀ òfurufú yìí ti ráwọ ìjì kékeré, a máa nílò láti yẹ̀bá kúrò nínú rẹ̀.” Pẹ̀lú èyí, ìpòrúru ọkàn náà kò fi ọ́ sílẹ̀. Àmọ́ ní báyìí, ó máa rọrùn fún ọ láti mú ọkàn kúrò níbi ìjì náà, nítorí ìdánilójú tí atukọ̀ ti ṣe sẹ́yìn nínú ìkéde rẹ̀.
Nígbàtí o bá mú àfojúsùn rẹ kúrò níbi ẹ̀rù tí o sì ń wo Ọlọ́run—ẹni tó lè tu'kọ̀ ayé wa láìsí ìjákulẹ̀—gbogbo ẹ̀rù ni yóò padà palọ́lọ́.
Ọlọ́run Aláàánú, nígbà tí ẹ̀rù bá ń bà mí, mo fẹ́ ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ. Jọ̀wọ́ pèsè gbogbo ǹkan tí mo nílò—bíi èrò, òtítọ́, àti ìgbani-níyànjú—láti lè ṣe èyí. Ìwọ kìíṣe Ọlọ́run ìdàrúdàpọ̀, bíkòṣe Ọlọ́run àlàáfíà. Nígbàkúùgbà tí n kò bá ní àlàáfíà, èyí túmọ̀ sí wípé mo ti jìnà s'ọ́dọ̀ rẹ. Ró mi lágbára láti wà nínú rẹ títí, ọ̀rọ̀ Rẹ yóò wà nínú mi pẹ̀lú, èyí tí yóò fún mi ní àǹfààní láti ní ìrírí àlàáfíà Rẹ. Ní orúkọ Kristi. Àmín.
Ṣé o jẹ̀gbádùn ètò yí àti àwọn àdúrà inú rẹ̀? A fẹ́ gbà ọ́ ní ìyànjú pẹ̀lú àwọn ìwàásù Tony Evans wọ̀nyí tó wà ní mp3 níbi ọ̀rọ̀-àsopọ̀ yí, èyí tó túbọ̀ ṣe àlàyé ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nípa ǹkan tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lónìí. Ṣáà fọwọ́ ba ọ̀rọ̀-àsopọ̀ yí.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
O lè borí ẹ̀rù. Dr. Tony Evans ma mú ẹ lọ́wọ́ dání ní ipa ọ̀nà sí òmìnira nínú ètò kíkà tó ní ìṣúra ọgbọ́n nínú yìí. Ṣàwarí ìgbé ayé aláyọ̀ àti tí àlàáfíà tí o ti ń pòǹgbẹ fún bí o ti ńṣe àmúlò àwọn ìlànà tí a gbé kalẹ̀ sínú ètò yí
More