Mú Ẹ̀rù Kúrò Lọ́nàÀpẹrẹ
Ǹjẹ́ o ṣe tán láti kọ́ bí o ṣe le wó ipá ẹ̀rù tí ọ̀tá ti kọ́ sí inú ẹ̀mí àti ọkàn rẹ palẹ̀? Jesu fún wa ní ìdáhùn. Oó lè wóo palẹ̀ nípa yí yí àwọn oun tí o yàn ní àyò padà. Oun tí Ó ún ṣe àlàyé rẹ̀ nìyí nínú Mátíù 6:33 nígbàtí Ó sọ pé, “Ṣùgbọ́n, ẹ kọ́kọ́ wá ìjọba Ọlọ́run ná àti òdodo rẹ̀, a ó sì fi gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí kún un fún yín pẹ̀lú. ”
Ni ọ̀rọ̀ míràn, tí o bá lo gbogbo àkókò àti okun rẹ fi dọ́gba pẹ̀lú oun ti Ọlọ́run Ńṣe láti fi tẹ ìjọba Rẹ̀ sí wájú nínú ayé, Ó pinu láti kín ọ lẹ́yìn lóríi àwọn nǹkan míràn nínú ayé tó lè mú ọ bẹ̀rù tàbí payá. Jesu ṣe àtẹnumọ́ yìí nígbàtí Ó sọ pé, “Nítorí náà, ẹ má ṣe àníyàn ọ̀la, ọ̀la ni yóò ṣe àníyàn ara rẹ̀. Wàhálà ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ti tó fún un.” (ẹsẹ̀ 34).
Ọlọ́run ń fún ọ ní ore-ọ̀fẹ́ ọjọ́ kan sí ọjọ́ kan. Kò ní fún ọ ní ore-ọ̀fẹ́ ti ọ̀la ní òní, nígbàtí o kò ní lọ rẹ̀. Kínì dì? Nítorí Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ sọ pé, “Nítorí ti àánú Rẹ kì í kùnà. Wọ́n jẹ́ ọ̀tún ní àrà-árọ̀; títóbi ni òtítọ́ Rẹ̀. compassions never fail. They are new every morning; great is Your faithfulness” (Ẹkún Jeremáyà 3:22–23). Nítorínáà, tí o bá ń jáyà tí o sì ń ṣe àníyàn nítoríi oun tí yóò ṣẹlẹ̀ lóla, ṣe ni òún sọ Fún Ọlọ́run pé o kò gbà Á gbọ́. Òún sọ fún pé Kò ṣeé fi ọkàn tán. Bákannáà ni òún rán èrò ọkàn rẹ lo sí koto ìnira àti ẹ̀rù tí yíò lọ́ra ìwà ìkúndùn wọn dípò kí ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti borí wọn. Láti ní ìbẹ̀rù fún ọ̀la ni láti sọ àlàáfíà àti ìṣẹ́gun òní nù. Fií sílẹ̀.
Ọlọ́run Aláàánú, Ràn mí lọ́wọ́ kín lè ṣàkíyèsí nígbàtí ẹ̀rù bá rápálá wọ inú èrò mi. Ràn mí lọ́wọ́ kí n le mú mọ́lẹ̀ àwọn èrò yí kí wọ́n tó máa pọ̀ tàbí dàgbà síi. Fún mi ní ọgbọ́n láti mọ oun tó mú ọgbọ́n dání àti oun tí kò mú ọgbọ́n dání, àti nínú ohun gbogbo Fún mi ní ipá láti fi ọkàn tán pé O tì mí lẹ́hìn gbọin gbọin. Mo fẹ́ kọ jú ẹ̀rù mi sí Ọ, nítorí náà jọ̀wọ́ Fún mi ní ore-ọ̀fẹ́ láti ṣe bẹ lónìí àti lojojúmọ́. Ní orúkọ Kristì. Àmín.
Ǹjẹ́ o gbádùn ounka ojojúmọ́ àti àdúrà yí? A fé ṣe ìwúrí fún ọ pẹ̀lú ìwàásù mẹ́ta ti Tony Evans ninu ìgba-ohùn-sílẹ̀ mp3 tí a le rí ká sílẹ̀ láti nípa títẹ okùnfà tíapèsè, ó tún wà jinlẹ̀ ohun tí a sọ lónìí. Kan ṣe àbẹ̀wò láti ibi.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
O lè borí ẹ̀rù. Dr. Tony Evans ma mú ẹ lọ́wọ́ dání ní ipa ọ̀nà sí òmìnira nínú ètò kíkà tó ní ìṣúra ọgbọ́n nínú yìí. Ṣàwarí ìgbé ayé aláyọ̀ àti tí àlàáfíà tí o ti ń pòǹgbẹ fún bí o ti ńṣe àmúlò àwọn ìlànà tí a gbé kalẹ̀ sínú ètò yí
More