Saamu 119:105-108

Saamu 119:105-108 YCB

Ọ̀rọ̀ rẹ ni fìtílà sí ẹsẹ̀ mi àti ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà mi Èmi ti ṣe ìbúra èmi sì ti tẹnumọ́ ọn wí pé èmi yóò máa tẹ̀lé òfin òdodo rẹ. A pọ́n mi lójú gidigidi; OLúWA, sọ mi di ààyè, gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ rẹ OLúWA, gba ìyìn àtinúwá ẹnu mi, kí o sì kọ́ mi ní òfin rẹ̀.