ORIN DAFIDI 119:105-108

ORIN DAFIDI 119:105-108 YCE

Ọ̀rọ̀ rẹ ni àtùpà fún ẹsẹ̀ mi, òun ni ìmọ́lẹ̀ sí ọ̀nà mi. Mo ti búra, n óo sì mú un ṣẹ, pé n óo máa pa òfin òdodo rẹ mọ́. Ojú ń pọ́n mi lọpọlọpọ, sọ mí di alààyè, OLUWA, gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Gba ẹbọ ìyìn àtọkànwá mi, OLUWA, kí o sì kọ́ mi ní ìlànà rẹ.