Òwe 8:1-11

Òwe 8:1-11 YCB

Ǹjẹ́ ọgbọ́n kò ha ń kígbe síta? Òye kò ha ń gbé ohùn rẹ sókè? Ní ibi gíga ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà ní ìkóríta, ní ó dúró; Ní ẹgbẹ́ ibodè tí ó wọ ìlú, ní ẹnu ibodè ni ó ń kígbe sókè: Sí i yín ẹ̀yin ènìyàn, ní mo ń kígbe pè; Mo gbé ohun mi sókè sí gbogbo ènìyàn, Ẹ̀yin aláìmọ̀kan, ẹ kọ́gbọ́n; ẹ̀yin aṣiwèrè, ẹ gba òye. Ẹ gbọ́, nítorí tí èmi ó sọ̀rọ̀ ohun iyebíye; Èmí ṣí ètè mi láti sọ ohun tí ó tọ́, Ẹnu mi ń sọ ohun tí í ṣe òtítọ́, nítorí ètè mi kórìíra ibi. Gbogbo ọ̀rọ̀ ẹnu mi ni ó tọ́, kò sí èyí tí ó jẹ́ ẹ̀tàn tàbí àyídáyidà níbẹ̀ Fún olóye gbogbo rẹ̀ ni ó tọ̀nà; wọ́n jẹ́ aláìlẹ́gàn fún gbogbo ẹni tí ó ní ìmọ̀. Yan ẹ̀kọ́ mi dípò fàdákà, ìmọ̀ dípò o wúrà àṣàyàn, Nítorí ọgbọ́n ṣe iyebíye jù iyùn lọ, kò sí ohun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ tí a sì le fiwé e.