Owe 8:1-11
Owe 8:1-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌGBỌ́N kò ha nkigbe bi? Oye kò ha gbé ohùn rẹ̀ soke bi? O duro li ori ibi-giga wọnni, lẹba ọ̀na, nibi ipa-ọ̀na wọnni. O nke li ẹnu-ọ̀na, ati ni ibode ilu, li atiwọ̀ oju ilẹkun. Ẹnyin enia li emi npè; ohùn mi si nkọ si awọn ọmọ enia. Ẹnyin òpe, ẹ mọ̀ ọgbọ́n: ati ẹnyin aṣiwere ki ẹnyin ki o ṣe alaiya oye. Ẹ gbọ́, nitori ti emi o sọ̀rọ ohun ti o dara, ati ṣiṣi ète mi yio sọ̀rọ ohun titọ. Nitori ti ẹnu mi yio sọ̀rọ otitọ; ìwa-buburu si ni irira fun ète mi. Ninu ododo ni gbogbo ọ̀rọ ẹnu mi; kò si ẹ̀tan kan tabi arekereke ninu wọn. Gbangba ni gbogbo wọn jasi fun ẹniti o yé, o si tọ́ fun awọn ti o nwá ìmọ ri. Gbà ẹkọ mi, kì si iṣe fadaka; si gbà ìmọ jù wura àṣayan lọ. Nitori ti ìmọ jù iyùn lọ; ohun gbogbo ti a le fẹ, kò si eyi ti a le fi we e.
Owe 8:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ǹjẹ́ ọgbọ́n kò ha ń kígbe síta? Òye kò ha ń gbé ohùn rẹ sókè? Ní ibi gíga ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà ní ìkóríta, ní ó dúró; Ní ẹgbẹ́ ibodè tí ó wọ ìlú, ní ẹnu ibodè ni ó ń kígbe sókè: Sí i yín ẹ̀yin ènìyàn, ní mo ń kígbe pè; Mo gbé ohun mi sókè sí gbogbo ènìyàn, Ẹ̀yin aláìmọ̀kan, ẹ kọ́gbọ́n; ẹ̀yin aṣiwèrè, ẹ gba òye. Ẹ gbọ́, nítorí tí èmi ó sọ̀rọ̀ ohun iyebíye; Èmí ṣí ètè mi láti sọ ohun tí ó tọ́, Ẹnu mi ń sọ ohun tí í ṣe òtítọ́, nítorí ètè mi kórìíra ibi. Gbogbo ọ̀rọ̀ ẹnu mi ni ó tọ́, kò sí èyí tí ó jẹ́ ẹ̀tàn tàbí àyídáyidà níbẹ̀ Fún olóye gbogbo rẹ̀ ni ó tọ̀nà; wọ́n jẹ́ aláìlẹ́gàn fún gbogbo ẹni tí ó ní ìmọ̀. Yan ẹ̀kọ́ mi dípò fàdákà, ìmọ̀ dípò o wúrà àṣàyàn, Nítorí ọgbọ́n ṣe iyebíye jù iyùn lọ, kò sí ohun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ tí a sì le fiwé e.
Owe 8:1-11 Yoruba Bible (YCE)
Ọgbọ́n ń pe eniyan, òye ń pariwo. Ó dúró ní ibi tí ó ga lẹ́bàá ọ̀nà, ati ní ojú ọ̀nà tóóró, ó ń kígbe lóhùn rara lẹ́nu ibodè àtiwọ ìlú, ó ń ké ní ẹnu ọ̀nà àbáwọlé pẹlu, ó ń wí pé: “Ẹ̀yin eniyan ni mò ń pè, gbogbo ọmọ eniyan ni mò ń ké sí. Ẹ̀yin òpè, ẹ kọ́ ọgbọ́n, ẹ̀yin òmùgọ̀, ẹ fetí sí òye. Ẹ tẹ́tí ẹ gbọ́, nítorí pé ọ̀rọ̀ pataki ni mo fẹ́ sọ. Ohun tí ó tọ́ ni n óo sì fi ẹnu mi sọ. Ọ̀rọ̀ òtítọ́ ni yóo ti ẹnu mi jáde, nítorí mo kórìíra ọ̀rọ̀ burúkú. Òdodo ni gbogbo ọ̀rọ̀ ẹnu mi, kò sí ìtànjẹ tabi ọ̀rọ̀ àrékérekè ninu wọn. Gbogbo ọ̀rọ̀ náà tọ́ lójú ẹni tí ó mòye, wọn kò sì ní àbùkù lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n ní ìmọ̀. Gba ẹ̀kọ́ mi dípò fadaka, ati ìmọ̀ dípò ojúlówó wúrà, nítorí ọgbọ́n níye lórí ju ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye lọ, kò sí ohun tí o fẹ́, tí a lè fi wé e.