ÌWÉ ÒWE 8

8
Yíyin Ọgbọ́n
1Ọgbọ́n ń pe eniyan,
òye ń pariwo.
2Ó dúró ní ibi tí ó ga lẹ́bàá ọ̀nà,
ati ní ojú ọ̀nà tóóró,
3ó ń kígbe lóhùn rara lẹ́nu ibodè àtiwọ ìlú,
ó ń ké ní ẹnu ọ̀nà àbáwọlé pẹlu,
ó ń wí pé:
4“Ẹ̀yin eniyan ni mò ń pè,
gbogbo ọmọ eniyan ni mò ń ké sí.
5Ẹ̀yin òpè, ẹ kọ́ ọgbọ́n,
ẹ̀yin òmùgọ̀, ẹ fetí sí òye.
6Ẹ tẹ́tí ẹ gbọ́, nítorí pé ọ̀rọ̀ pataki ni mo fẹ́ sọ.
Ohun tí ó tọ́ ni n óo sì fi ẹnu mi sọ.
7Ọ̀rọ̀ òtítọ́ ni yóo ti ẹnu mi jáde,
nítorí mo kórìíra ọ̀rọ̀ burúkú.
8Òdodo ni gbogbo ọ̀rọ̀ ẹnu mi,#Owe 1:20-21
kò sí ìtànjẹ tabi ọ̀rọ̀ àrékérekè ninu wọn.
9Gbogbo ọ̀rọ̀ náà tọ́ lójú ẹni tí ó mòye,
wọn kò sì ní àbùkù lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n ní ìmọ̀.
10Gba ẹ̀kọ́ mi dípò fadaka,
ati ìmọ̀ dípò ojúlówó wúrà,
11nítorí ọgbọ́n níye lórí ju ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye lọ,
kò sí ohun tí o fẹ́, tí a lè fi wé e.
12Èmi, ọgbọ́n, òye ni mò ń bá gbélé,
mo ṣe àwárí ìmọ̀ ati làákàyè.
13Ẹni tó bá bẹ̀rù OLUWA, yóo kórìíra ibi,
mo kórìíra ìwà ìgbéraga, ọ̀nà ibi ati ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́.
14Èmi ni mo ní ìmọ̀ràn ati ọgbọ́n tí ó yè kooro,
mo sì ní òye ati agbára.
15Nípasẹ̀ mi ni àwọn ọba fi ń ṣe ìjọba,
tí àwọn alákòóso sì ń pàṣẹ òdodo.
16Nípasẹ̀ mi ni àwọn olórí ń ṣe àkóso,
gbogbo àwọn ọlọ́lá sì ń ṣe àkóso ayé.
17Mo fẹ́ràn gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ràn mi,
àwọn tí wọ́n bá fi tọkàntọkàn wá mi yóo sì rí mi.
18Ọrọ̀ ati iyì wà níkàáwọ́ mi,
ọrọ̀ tíí tọ́jọ́, ati ibukun.
19Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ,
àyọrísí mi sì dára ju ojúlówó fadaka lọ.
20Ọ̀nà òdodo ni èmi ń rìn,
ojú ọ̀nà tí ó tọ́ ni mò ń tọ̀.
21Èmi a máa fún àwọn tí wọ́n fẹ́ mi ní ọrọ̀,
n óo máa mú kí ìṣúra wọn kún.
22Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá ayé ni OLUWA ti dá mi,#Sir 1:4; Ifi 3:14
kí ó tó bẹ̀rẹ̀ àwọn iṣẹ́ àrà rẹ̀.
23Láti ayébáyé ni a ti yàn mí,
láti ìbẹ̀rẹ̀, kí á tó dá ayé rárá.
24Kí ibú omi tó wà ni mo ti wà,
nígbà tí kò tíì sí àwọn orísun omi.
25Kí á tó dá àwọn òkè ńlá sí ààyè wọn,
kí àwọn òkè kéékèèké tó wà, ni mo ti wà.
26Kí Ọlọrun tó dá ayé, ati pápá oko,
kí ó tó dá erùpẹ̀ ilẹ̀.
27Mo wà níbẹ̀ nígbà tí ó dá ojú ọ̀run sí ààyè rẹ̀,
tí ó ṣe àmì bìrìkìtì sórí ibú,
ní ibi tí ó dàbí ẹni pé ilẹ̀ ati ọ̀run ti pàdé,
28nígbà tí ó ṣe awọsanma lọ́jọ̀,
tí ó fi ìpìlẹ̀ orísun omi sọ ilẹ̀,
29nígbà tí ó pààlà sí ibi tí òkun gbọdọ̀ kọjá,
kí omi má baà kọjá ààyè rẹ̀.
Nígbà tí ó sàmì sí ibi tí ìpìlẹ̀ ayé wà,
30èmi ni oníṣẹ́ ọnà tí mo wà lọ́dọ̀ rẹ̀,
Inú mi a máa dùn lojoojumọ,
èmi a sì máa yọ̀ níwájú rẹ̀ nígbà gbogbo.
31Mo láyọ̀ ninu ayé tí àwọn ẹ̀dá alààyè ń gbé,#Ọgb 9:9; Sir 24:3-6
inú mi sì ń dùn sí àwọn ọmọ eniyan.
32“Nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ fetí sí mi,#Sir 14:20-27
ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà mi.
33Ẹ gbọ́ ìtọ́ni, kí ẹ sì kọ́gbọ́n,
ẹ má sì ṣe àìnáání rẹ̀.
34Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá gbọ́ tèmi,
tí ó ń ṣọ́nà lojoojumọ ní ẹnu ọ̀nà àgbàlá mi,
tí ó dúró sí ẹnu ọ̀nà ilé mi.
35Ẹni tí ó rí mi, rí ìyè,
ó sì rí ojurere lọ́dọ̀ OLUWA,
36ṣugbọn ẹni tí kò bá rí mi, ó pa ara rẹ̀ lára,
gbogbo àwọn tí wọ́n kórìíra mi, ikú ni wọ́n fẹ́ràn.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÌWÉ ÒWE 8: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀