ÌWÉ ÒWE 9
9
Ọgbọ́n ati Wèrè
1Ọgbọ́n ti kọ́lé,
ó ti gbé àwọn òpó rẹ̀ mejeeje nàró.
2Ó ti pa ẹran rẹ̀,
ó ti pọn ọtí waini rẹ̀,
ó sì ti tẹ́ tabili rẹ̀ kalẹ̀.
3Ó ti rán àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀
kí wọn lọ máa kígbe lórí àwọn òkè láàrin ìlú pé:
4“Ẹ yà síbí ẹ̀yin òpè!”
Ó sọ fún ẹni tí kò lọ́gbọ́n pé,
5“Máa bọ̀, wá jẹ lára oúnjẹ mi,
kí o sì mu ninu ọtí waini tí mo ti pò.
6Fi àìmọ̀kan sílẹ̀, kí o sì yè,
kí o máa rin ọ̀nà làákàyè.”
7Ẹni tí ń tọ́ oníyẹ̀yẹ́ eniyan sọ́nà fẹ́ kan àbùkù,
ẹni tí ń bá ìkà eniyan wí ń wá ìfarapa fún ara rẹ̀.
8Má ṣe bá oníyẹ̀yẹ́ eniyan wí,
kí ó má baà kórìíra rẹ,
bá ọlọ́gbọ́n wí, yóo sì fẹ́ràn rẹ.
9Kọ́ ọlọ́gbọ́n, yóo tún gbọ́n sí i,
kọ́ olódodo, yóo sì tún ní ìmọ̀ kún ìmọ̀.
10Ìbẹ̀rù OLUWA ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n,#Job 28:28; O. Daf 111:10; Owe 1:7
ìmọ̀ Ẹni Mímọ́ sì ni làákàyè.
11Nípasẹ̀ mi ẹ̀mí rẹ yóo gùn.
Ọpọlọpọ ọdún ni o óo sì lò lórí ilẹ̀ alààyè.
12Bí o bá gbọ́n, o óo jèrè ọgbọ́n rẹ,
Bí o bá sì jẹ́ pẹ̀gànpẹ̀gàn, ìwọ nìkan ni o óo jèrè rẹ̀.
13Aláriwo ni obinrin tí kò gbọ́n,
oníwọ̀ra ni, kò sì ní ìtìjú.
14Á máa jókòó lẹ́nu ọ̀nà ilé rẹ̀,
á jókòó ní ibi tí ó ga láàrin ìlú.
15A máa kígbe pe àwọn tí ń kọjá lọ,
àwọn tí ń bá tiwọn lọ jẹ́ẹ́jẹ́ wọn, pé,
16“Ẹni tí ó bá jẹ́ aláìmọ̀kan, kí ó máa bọ̀!”
Ó sì wí fún àwọn òmùgọ̀ pé,
17“Omi tí eniyan bá jí mu a máa dùn,
oúnjẹ tí a bá jí jẹ, oyinmọmọ ni.”
18Àwọn tí wọ́n bá yà sọ́dọ̀ rẹ̀ kò ní mọ̀ pé ikú wà ní ilé rẹ̀,
ati pé inú isà òkú ni àwọn tí wọ́n bá wọ ilé rẹ̀ wọ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ÌWÉ ÒWE 9: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010