ÌWÉ ÒWE 10

10
Àwọn Òwe Solomoni
1Àwọn òwe Solomoni nìwọ̀nyí:
Ọlọ́gbọ́n ọmọ á máa mú kí inú baba rẹ̀ dùn,
ṣugbọn òmùgọ̀ ọmọ a máa kó ìbànújẹ́ bá ìyá rẹ̀.
2Ọrọ̀ tí a kójọ lọ́nà èrú kò lérè,
ṣugbọn òdodo a máa gba eniyan lọ́wọ́ ikú.
3OLUWA kì í jẹ́ kí ebi pa olódodo,
ṣugbọn ó máa ń da ìfẹ́ ọkàn eniyan burúkú rú.
4Ìmẹ́lẹ́ máa ń fa òṣì,
ṣugbọn ẹni tí ó bá tẹpá mọ́ṣẹ́ yóo di ọlọ́rọ̀.
5Ọlọ́gbọ́n ní ọmọ tí ó kórè ní àkókò ìkórè,
ṣugbọn ọmọ tí ó bá ń sùn lákòókò ìkórè
a máa kó ìtìjú báni.
6Ibukun wà lórí olódodo,
ṣugbọn eniyan burúkú a máa fi ìwà ìkà sinu,
a sì máa sọ̀rọ̀ rere jáde lẹ́nu.
7Ayọ̀ ni ìrántí olódodo,
ṣugbọn orúkọ eniyan burúkú yóo di ohun ìgbàgbé.
8Ọlọ́gbọ́n a máa pa òfin mọ́,
ṣugbọn òmùgọ̀ onísọkúsọ yóo di ẹni ìparun.
9Ẹni tí ó bá jẹ́ olóòótọ́ eniyan, yóo máa rìn láìfòyà,
ṣugbọn àṣírí alágàbàgebè yóo tú.
10Ẹni tí bá ń ṣẹ́jú sí ni láti sọ̀rọ̀ èké, a máa dá ìjàngbọ̀n sílẹ̀,
ṣugbọn ẹni tí bá ń báni wí ní gbangba, ń wá alaafia.
11Ẹnu olódodo dàbí orísun omi ìyè,
ṣugbọn eniyan burúkú a máa fi ìwà ìkà sinu,
a sì máa sọ̀rọ̀ rere jáde lẹ́nu.
12Ìkórìíra a máa rú ìjà sókè,#Jak 5:20; 1 Pet 4:8
ṣugbọn ìfẹ́ a máa fojú fo gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ dá.
13Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n níí máa ń jáde lẹ́nu ẹni tí ó ní òye,
ṣugbọn kùmọ̀ ló yẹ ẹ̀yìn ẹni tí kò gbọ́n.
14Ọlọ́gbọ́n eniyan a máa wá ìmọ̀ kún ìmọ̀,
ṣugbọn ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ máa ń fa ìparun mọ́ra.
15Ohun ìní ọlọ́rọ̀ ni ààbò rẹ̀,
ṣugbọn àìní talaka ni yóo pa talaka run.
16Èrè àwọn olódodo a máa fa ìyè,
ṣugbọn èrè àwọn eniyan burúkú a máa fà wọ́n sinu ẹ̀ṣẹ̀.
17Ẹni tí ó bá gba ìtọ́ni wà ní ọ̀nà ìyè,
ṣugbọn ẹni tí ó bá kọ ìbáwí yóo ṣìnà.
18Ẹni tí ó di eniyan sinu jẹ́ ẹlẹ́tàn eniyan,
ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́, òmùgọ̀ ni.
19Bí ọ̀rọ̀ bá ti pọ̀ jù, àṣìsọ a máa wọ̀ ọ́,
ṣugbọn ẹni tí ó bá kó ẹnu ara rẹ̀ ní ìjánu, ọlọ́gbọ́n ni.
20Ọ̀rọ̀ ẹnu olódodo dàbí fadaka,
ṣugbọn èrò ọkàn eniyan burúkú kò já mọ́ nǹkankan.
21Ọ̀rọ̀ ẹnu olódodo a máa ṣe ọpọlọpọ eniyan ní anfaani,
ṣugbọn òmùgọ̀ eniyan a máa kú nítorí àìgbọ́n.
22Ibukun OLUWA ní ń mú ni í là,
kì í sì í fi làálàá kún un.
23Ibi ṣíṣe a máa dùn mọ́ òmùgọ̀,
ṣugbọn ìwà ọgbọ́n ni ayọ̀ fún ẹni tí ó mòye.
24Ohun tí eniyan burúkú ń bẹ̀rù ni yóo dé bá a,
ohun tí olódodo ń fẹ́ ni yóo sì rí gbà.
25Nígbà tí ìjì líle bá ń jà, a gbá ẹni ibi lọ,
ṣugbọn olódodo a fẹsẹ̀ múlẹ̀ títí lae.
26Bí ọtí kíkan ti rí sí eyín,
ati bí èéfín ti rí sí ojú,
bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ rí sí ẹni tí ó bẹ̀ ẹ́ níṣẹ́.
27Ìbẹ̀rù OLUWA a máa mú kí ẹ̀mí eniyan gùn,
ṣugbọn ìgbé ayé eniyan burúkú yóo kúrú.
28Ìrètí olódodo yóo yọrí sí ayọ̀,
ṣugbọn ìrètí ẹni ibi yóo jásí òfo.
29OLUWA jẹ́ agbára fún àwọn tí ọ̀nà wọn tọ́,
ṣugbọn ìparun ni fún àwọn oníṣẹ́ ibi.
30Gbọningbọnin ni olódodo yóo dúró,
ṣugbọn ẹni ibi kò ní lè gbé ilẹ̀ náà.
31Ẹnu olódodo kún fún ọ̀rọ̀ ọgbọ́n,
ṣugbọn ẹnu alaiṣootọ ni a pamọ́.
32Olódodo mọ ohun tí ó dára láti sọ,
ṣugbọn ti eniyan burúkú kò ju ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn lọ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÌWÉ ÒWE 10: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa