1
ÌWÉ ÒWE 10:22
Yoruba Bible
Ibukun OLUWA ní ń mú ni í là, kì í sì í fi làálàá kún un.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 10:22
2
ÌWÉ ÒWE 10:19
Bí ọ̀rọ̀ bá ti pọ̀ jù, àṣìsọ a máa wọ̀ ọ́, ṣugbọn ẹni tí ó bá kó ẹnu ara rẹ̀ ní ìjánu, ọlọ́gbọ́n ni.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 10:19
3
ÌWÉ ÒWE 10:12
Ìkórìíra a máa rú ìjà sókè, ṣugbọn ìfẹ́ a máa fojú fo gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ dá.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 10:12
4
ÌWÉ ÒWE 10:4
Ìmẹ́lẹ́ máa ń fa òṣì, ṣugbọn ẹni tí ó bá tẹpá mọ́ṣẹ́ yóo di ọlọ́rọ̀.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 10:4
5
ÌWÉ ÒWE 10:17
Ẹni tí ó bá gba ìtọ́ni wà ní ọ̀nà ìyè, ṣugbọn ẹni tí ó bá kọ ìbáwí yóo ṣìnà.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 10:17
6
ÌWÉ ÒWE 10:9
Ẹni tí ó bá jẹ́ olóòótọ́ eniyan, yóo máa rìn láìfòyà, ṣugbọn àṣírí alágàbàgebè yóo tú.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 10:9
7
ÌWÉ ÒWE 10:27
Ìbẹ̀rù OLUWA a máa mú kí ẹ̀mí eniyan gùn, ṣugbọn ìgbé ayé eniyan burúkú yóo kúrú.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 10:27
8
ÌWÉ ÒWE 10:3
OLUWA kì í jẹ́ kí ebi pa olódodo, ṣugbọn ó máa ń da ìfẹ́ ọkàn eniyan burúkú rú.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 10:3
9
ÌWÉ ÒWE 10:25
Nígbà tí ìjì líle bá ń jà, a gbá ẹni ibi lọ, ṣugbọn olódodo a fẹsẹ̀ múlẹ̀ títí lae.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 10:25
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò