ÌWÉ ÒWE 7

7
1Ọmọ mi, pa ọ̀rọ̀ mi mọ́,
kí o sì fi òfin mi sinu ọkàn rẹ.
2Pa òfin mi mọ́, kí o lè yè,
pa ẹ̀kọ́ mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹyin ojú rẹ,
3wé wọn mọ́ ìka rẹ,
kí o sì kọ wọ́n sí oókan àyà rẹ.
4Sọ fún ọgbọ́n pé, “Ìwọ ni arabinrin mi,”
kí o sì pe ìmọ̀ ní ọ̀rẹ́ kòríkòsùn rẹ,
5kí wọ́n baà lè pa ọ́ mọ́,
kúrò lọ́dọ̀ alágbèrè obinrin,
ati kúrò lọ́wọ́ onírìnkurìn pẹlu ọ̀rọ̀ dídùn rẹ̀.
Obinrin Oníṣekúṣe
6Mo yọjú wo ìta,
láti ojú fèrèsé ilé mi.
7Mo rí àwọn ọ̀dọ́ tí wọn kò ní ìrírí,
mo ṣe akiyesi pé láàrin wọn,
ọmọkunrin kan wà tí kò gbọ́n.
8Ó ń lọ ní òpópónà, lẹ́bàá kọ̀rọ̀ ilé alágbèrè obinrin náà,
9ní àṣáálẹ́, nígbà tí ọjọ́ ń pofírí,
tí ilẹ̀ ti ń ṣú, tí òkùnkùn ti ń kùn.
10Obinrin kan lọ pàdé rẹ̀,
ó wọ aṣọ aṣẹ́wó,
ọkàn rẹ̀ kún fún ẹ̀tàn.
11Ó jẹ́ aláriwo ati onírìnkurìn obinrin,
kì í gbélé rẹ̀.
12Bí ó ti ń rìn kiri lójú pópó,
bẹ́ẹ̀ ni yóo máa lọ, tí yóo máa bọ̀ láàrin ọjà,
yóo máa dọdẹ kiri ní gbogbo kọ̀rọ̀.
13Yóo bá dì mọ́ ọmọkunrin tí kò gbọ́n náà, yóo fi ẹnu kò ó lẹ́nu,
yóo wí pẹlu ainitiju pé,
14“Mo ti rú ẹbọ alaafia,
mo sì ti san ẹ̀jẹ́ mi lónìí.
15Nítorí náà, mo wá pàdé rẹ,
mo fi ìlara wá ọ, mo sì rí ọ.
16Mo ti tẹ́ aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ aláràbarà ti ilẹ̀ Ijipti sórí ibùsùn mi.
17Mo tú turari olóòórùn dídùn ati òjíá, aloe ati sinamoni, sórí ibùsùn mi.
18Wá, jẹ́ kí á ṣeré ìfẹ́
títí ilẹ̀ yóo fi mọ́,
jẹ́ kí á fi ìfẹ́ gbádùn ara wa.
19Ọkọ mi kò sí nílé,
ó ti lọ sí ìrìn àjò, ọ̀nà rẹ̀ sì jìn.
20Ó mú owó pupọ lọ́wọ́,
kò ní dé títí òṣùpá yóo fi di àrànmọ́jú.”
21Ó rọ̀ ọ́ pẹlu ọpọlọpọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn,
ó fi ọ̀rọ̀ dídùn mú un.
22Lẹsẹkẹsẹ, ọmọkunrin náà bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀lé e,
bíi mààlúù tí wọn ń fà lọ pa,
tabi bí àgbọ̀nrín tí ó tẹsẹ̀ bọ tàkúté,
23títí tí ọfà fi wọ̀ ọ́ ninu
bí ẹyẹ tí ń yára bọ́ sinu okùn,
láì mọ̀ pé ó lè ṣe ikú pa òun.
24Nisinsinyii, ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin ọmọ mi,
ẹ farabalẹ̀ gbọ́ nǹkan tí mò ń sọ.
25Ẹ má jẹ́ kí ọkàn yín lọ sọ́dọ̀ irú obinrin bẹ́ẹ̀,
ẹ má ṣèèṣì yà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.
26Ọ̀pọ̀ ni àwọn tí ó ti sọ di ẹni ilẹ̀,
ọpọlọpọ àwọn alágbára ni ó ti ṣe ikú pa.
27Ọ̀nà isà òkú tààrà ni ilé rẹ̀,
ilé rẹ̀ ni ọ̀nà àbùjá sí ìparun.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÌWÉ ÒWE 7: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀