Òwe 8
8
Ọgbọ́n n fi ìpè síta
1 Ǹjẹ́ ọgbọ́n kò ha ń kígbe síta?
Òye kò ha ń gbé ohùn rẹ sókè?
2Ní ibi gíga ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà
ní ìkóríta, ní ó dúró;
3Ní ẹgbẹ́ ibodè tí ó wọ ìlú,
ní ẹnu ibodè ni ó ń kígbe sókè:
4Sí i yín ẹ̀yin ènìyàn, ní mo ń kígbe pè;
Mo gbé ohun mi sókè sí gbogbo ènìyàn,
5Ẹ̀yin aláìmọ̀kan, ẹ kọ́gbọ́n;
ẹ̀yin aṣiwèrè, ẹ gba òye.
6Ẹ gbọ́, nítorí tí èmi ó sọ̀rọ̀ ohun iyebíye;
Èmí ṣí ètè mi láti sọ ohun tí ó tọ́,
7Ẹnu mi ń sọ ohun tí í ṣe òtítọ́,
nítorí ètè mi kórìíra ibi.
8Gbogbo ọ̀rọ̀ ẹnu mi ni ó tọ́,
kò sí èyí tí ó jẹ́ ẹ̀tàn tàbí àyídáyidà níbẹ̀
9Fún olóye gbogbo rẹ̀ ni ó tọ̀nà;
wọ́n jẹ́ aláìlẹ́gàn fún gbogbo ẹni tí ó ní ìmọ̀.
10Yan ẹ̀kọ́ mi dípò fàdákà,
ìmọ̀ dípò o wúrà àṣàyàn,
11Nítorí ọgbọ́n ṣe iyebíye jù iyùn lọ,
kò sí ohun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ tí a sì le fiwé e.
12“Èmi, ọgbọ́n ń gbé pẹ̀lú òye;
mo ní ìmọ̀ àti ọgbọ́n-inú.
13Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìkórìíra ibi
mo kórìíra ìgbéraga àti agídí,
ìwà ibi àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.
14Ìmọ̀ràn àti ọgbọ́n tí ó yè kooro jẹ́ tèmi
mo ní òye àti agbára.
15Nípasẹ̀ mi ni ọba ń ṣàkóso
tí àwọn aláṣẹ sì ń ṣe òfin tí ó dára
16Nípasẹ̀ mi àwọn ọmọ-aládé ń ṣàkóso
àti gbogbo ọlọ́lá tí ń ṣàkóso ilẹ̀ ayé.
17Mo fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn mi
àwọn tí ó sì wá mi rí mi.
18Lọ́dọ̀ mi ni ọrọ̀ àti ọlá wà
ọrọ̀ tí í tọ́jọ́ àti ìgbéga rere.
19Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ;
ohun tí mò ń mú wá ju àṣàyàn fàdákà lọ.
20Mò ń rìn ní ọ̀nà òdodo,
ní ojú ọ̀nà òtítọ́,
21Mò ń fi ọrọ̀ fún gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn mi
mo sì ń mú kí ilé ìṣúra wọn kún.
22“Èmi ni Olúwa kọ́kọ́ dá nínú iṣẹ́ rẹ̀.
Ṣáájú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ àtijọ́;
23A ti yàn mí láti ayérayé,
láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, kí ayé tó bẹ̀rẹ̀.
24Nígbà tí kò tí ì sí Òkun, ni a ti bí mi
nígbà tí kò tí ì sí ìsun tí ó ní omi nínú;
25kí a tó fi àwọn òkè sí ipò wọn,
ṣáájú àwọn òkè ni a ti bí mi,
26kí ó tó dá ilẹ̀ ayé tàbí àwọn oko rẹ̀
tàbí èyíkéyìí nínú eruku ayé.
27Mo wà níbẹ̀ nígbà tí ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn,
nígbà tí ó fi òṣùwọ̀n àyíká sórí ibú omi,
28Nígbà tí ó ṣẹ̀dá òfúrufú lókè
tí ó sì fi orísun ibú omi sí ipò rẹ̀ láì le è yẹsẹ̀,
29Nígbà tí ó ṣe ààlà fún omi Òkun
kí omi má ba à kọjá ààlà àṣẹ rẹ̀,
àti nígbà tí ó pààlà ìpìlẹ̀ ayé.
30Nígbà náà èmi ni gbẹ́nàgbẹ́nà ẹ̀gbẹ́ rẹ̀
mo kún fún inú dídùn lójoojúmọ́,
mo ń yọ̀ nígbà gbogbo níwájú rẹ̀.
31Mo ń yọ̀ nínú gbogbo àgbáyé tí ó dá
mo sì ní inú dídùn sí àwọn ọmọ ènìyàn.
32“Nítorí náà báyìí, ẹ̀yin ọmọ mi,
ìbùkún ni fún àwọn tí ó pa ọ̀nà mi mọ́,
33Fetí sí ìtọ́sọ́nà mi kí o sì gbọ́n;
má ṣe pa á tì sápá kan.
34Ìbùkún ni fún ẹni tí ó fetísílẹ̀ sí mi,
tí ń ṣọ́nà ní ẹnu-ọ̀nà mi lójoojúmọ́,
tí ń dúró ní ẹnu-ọ̀nà mi.
35Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi rí ìyè
ó sì rí ojúrere gbà lọ́dọ̀ Olúwa.
36Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti rí ń pa ara rẹ̀ lára
gbogbo ẹni tí ó kórìíra mi fẹ́ ikú.”
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Òwe 8: YCB
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.