ÌWÉ ÒWE 8:1-11

ÌWÉ ÒWE 8:1-11 YCE

Ọgbọ́n ń pe eniyan, òye ń pariwo. Ó dúró ní ibi tí ó ga lẹ́bàá ọ̀nà, ati ní ojú ọ̀nà tóóró, ó ń kígbe lóhùn rara lẹ́nu ibodè àtiwọ ìlú, ó ń ké ní ẹnu ọ̀nà àbáwọlé pẹlu, ó ń wí pé: “Ẹ̀yin eniyan ni mò ń pè, gbogbo ọmọ eniyan ni mò ń ké sí. Ẹ̀yin òpè, ẹ kọ́ ọgbọ́n, ẹ̀yin òmùgọ̀, ẹ fetí sí òye. Ẹ tẹ́tí ẹ gbọ́, nítorí pé ọ̀rọ̀ pataki ni mo fẹ́ sọ. Ohun tí ó tọ́ ni n óo sì fi ẹnu mi sọ. Ọ̀rọ̀ òtítọ́ ni yóo ti ẹnu mi jáde, nítorí mo kórìíra ọ̀rọ̀ burúkú. Òdodo ni gbogbo ọ̀rọ̀ ẹnu mi, kò sí ìtànjẹ tabi ọ̀rọ̀ àrékérekè ninu wọn. Gbogbo ọ̀rọ̀ náà tọ́ lójú ẹni tí ó mòye, wọn kò sì ní àbùkù lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n ní ìmọ̀. Gba ẹ̀kọ́ mi dípò fadaka, ati ìmọ̀ dípò ojúlówó wúrà, nítorí ọgbọ́n níye lórí ju ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye lọ, kò sí ohun tí o fẹ́, tí a lè fi wé e.