Òwe 18:16-18

Òwe 18:16-18 YCB

Ẹ̀bùn máa ń ṣí ọ̀nà fún ẹni tí ń fún ni lẹ́bùn a sì mú un wọlé sí ọ̀dọ̀ àwọn olókìkí. Ẹni tí ó kọ́kọ́ rọjọ́ máa ń dàbí i pé ó jàre títí ẹlòmíràn yóò fi bọ́ síwájú kí ó sì tú àṣírí gbogbo. Ìbò dídì máa ń parí ìjà a sì mú kí àwọn alátakò méjì jìnnà sí ara wọn.