ÌWÉ ÒWE 18:16-18

ÌWÉ ÒWE 18:16-18 YCE

Ẹ̀bùn a máa ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ẹni tí ń fúnni lẹ́bùn, a sì mú un dé iwájú ẹni gíga. Ẹni tí ó bá kọ́kọ́ rojọ́ níí dàbí ẹni tí ó jàre, títí tí ẹnìkejì yóo fi bi í ní ìbéèrè, Gègé ṣíṣẹ́ a máa yanjú ọ̀rọ̀ a sì parí gbolohun asọ̀ láàrin àwọn alágbára.