Owe 18:16-18

Owe 18:16-18 YBCV

Ọrẹ enia a ma fi àye fun u, a si mu u wá siwaju awọn enia nla. Ẹnikini ninu ẹjọ rẹ̀ a dabi ẹnipe o jare, ṣugbọn ẹnikeji rẹ̀ a wá, a si hudi rẹ̀ silẹ. Keké mu ìja pari, a si làja lãrin awọn alagbara.