Owe 18:16-18
Owe 18:16-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ̀bùn máa ń ṣí ọ̀nà fún ẹni tí ń fún ni lẹ́bùn a sì mú un wọlé sí ọ̀dọ̀ àwọn olókìkí. Ẹni tí ó kọ́kọ́ rọjọ́ máa ń dàbí i pé ó jàre títí ẹlòmíràn yóò fi bọ́ síwájú kí ó sì tú àṣírí gbogbo. Ìbò dídì máa ń parí ìjà a sì mú kí àwọn alátakò méjì jìnnà sí ara wọn.
Owe 18:16-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọrẹ enia a ma fi àye fun u, a si mu u wá siwaju awọn enia nla. Ẹnikini ninu ẹjọ rẹ̀ a dabi ẹnipe o jare, ṣugbọn ẹnikeji rẹ̀ a wá, a si hudi rẹ̀ silẹ. Keké mu ìja pari, a si làja lãrin awọn alagbara.
Owe 18:16-18 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀bùn a máa ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ẹni tí ń fúnni lẹ́bùn, a sì mú un dé iwájú ẹni gíga. Ẹni tí ó bá kọ́kọ́ rojọ́ níí dàbí ẹni tí ó jàre, títí tí ẹnìkejì yóo fi bi í ní ìbéèrè, Gègé ṣíṣẹ́ a máa yanjú ọ̀rọ̀ a sì parí gbolohun asọ̀ láàrin àwọn alágbára.