Esekiẹli 28:1-5

Esekiẹli 28:1-5 YCB

Ọ̀rọ̀ OLúWA tún tọ̀ mí wá wí pé: “Ọmọ ènìyàn, sọ fún ọmọ-aládé Tire pé, ‘Báyìí ní OLúWA Olódùmarè wí: “ ‘Nítorí tí ọkàn rẹ gbé sókè sí mi, ìwọ wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run; Èmi jókòó sí orí ìtẹ́ òrìṣà, ní àárín gbùngbùn Òkun.” Ṣùgbọ́n ènìyàn ni ọ́, kì i ṣe òrìṣà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ rò pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run. Ìwọ gbọ́n ju Daniẹli lọ bí? Ṣé kò sí àṣírí kan tí ó pamọ́ fún ọ? Pẹ̀lú ọgbọ́n àti ìmọ̀ rẹ, ìwọ tí jèrè ọrọ̀ fún ara rẹ, àti àkójọpọ̀ wúrà àti fàdákà, nínú àwọn ilé ìṣúra rẹ. Nípa ọgbọ́n rẹ ńlá àti nípa òwò rẹ, ìwọ ti sọ ọrọ̀ rẹ di púpọ̀, àti nítorí ọrọ̀ rẹ di púpọ̀, ọkàn rẹ gbé sókè, nítorí ọrọ̀ rẹ.