Esek 28:1-5
Esek 28:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọ̀rọ̀ OLúWA tún tọ̀ mí wá wí pé: “Ọmọ ènìyàn, sọ fún ọmọ-aládé Tire pé, ‘Báyìí ní OLúWA Olódùmarè wí: “ ‘Nítorí tí ọkàn rẹ gbé sókè sí mi, ìwọ wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run; Èmi jókòó sí orí ìtẹ́ òrìṣà, ní àárín gbùngbùn Òkun.” Ṣùgbọ́n ènìyàn ni ọ́, kì i ṣe òrìṣà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ rò pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run. Ìwọ gbọ́n ju Daniẹli lọ bí? Ṣé kò sí àṣírí kan tí ó pamọ́ fún ọ? Pẹ̀lú ọgbọ́n àti ìmọ̀ rẹ, ìwọ tí jèrè ọrọ̀ fún ara rẹ, àti àkójọpọ̀ wúrà àti fàdákà, nínú àwọn ilé ìṣúra rẹ. Nípa ọgbọ́n rẹ ńlá àti nípa òwò rẹ, ìwọ ti sọ ọrọ̀ rẹ di púpọ̀, àti nítorí ọrọ̀ rẹ di púpọ̀, ọkàn rẹ gbé sókè, nítorí ọrọ̀ rẹ.
Esek 28:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọ̀RỌ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe, Ọmọ enia, sọ fun ọmọ-alade Tire pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitori ti ọkàn rẹ gbe soke, ati ti iwọ si wipe, Ọlọrun li emi, emi joko ni ibujoko Ọlọrun, larin okun; ṣugbọn enia ni iwọ, iwọ kì isi ṣe Ọlọrun, bi o tilẹ gbe ọkàn rẹ soke bi ọkàn Ọlọrun. Wo o, iwọ sa gbọn ju Danieli lọ; kò si si ohun ikọ̀kọ ti o le fi ara sin fun ọ. Ọgbọ́n rẹ ati oye rẹ li o fi ni ọrọ̀, o si ti ni wura ati fadáka sinu iṣura rẹ: Nipa ọgbọ́n rẹ nla ati nipa òwo rẹ li o ti fi sọ ọrọ̀ rẹ di púpọ, ọkàn rẹ si gbe soke nitori ọrọ̀ rẹ.

Esek 28:1-5 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ fún ọba Tire pé OLUWA ní, ‘Nítorí pé ìgbéraga kún ọkàn rẹ, o sì ti sọ ara rẹ di oriṣa, o sọ pé o jókòó ní ibùjókòó àwọn oriṣa láàrin òkun; bẹ́ẹ̀ sì ni eniyan ni ọ́, o kì í ṣe oriṣa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ò ń rò pé o gbọ́n bí àwọn oriṣa, nítòótọ́, o gbọ́n ju Daniẹli lọ, kò sì sí ohun àṣírí kan tí ó ṣú ọ lójú. Nípa ọgbọ́n ati ìmọ̀ rẹ, o ti kó ọpọlọpọ ọrọ̀ jọ fún ara rẹ, o sì kó wúrà ati fadaka jọ sinu ilé ìṣúra rẹ. O ti ní àníkún ọrọ̀ nítorí ọgbọ́n rẹ ninu òwò ṣíṣe, ìgbéraga sì ti kún ọkàn rẹ nítorí ọrọ̀ rẹ.’