OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ fún ọba Tire pé OLUWA ní, ‘Nítorí pé ìgbéraga kún ọkàn rẹ, o sì ti sọ ara rẹ di oriṣa, o sọ pé o jókòó ní ibùjókòó àwọn oriṣa láàrin òkun; bẹ́ẹ̀ sì ni eniyan ni ọ́, o kì í ṣe oriṣa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ò ń rò pé o gbọ́n bí àwọn oriṣa, nítòótọ́, o gbọ́n ju Daniẹli lọ, kò sì sí ohun àṣírí kan tí ó ṣú ọ lójú. Nípa ọgbọ́n ati ìmọ̀ rẹ, o ti kó ọpọlọpọ ọrọ̀ jọ fún ara rẹ, o sì kó wúrà ati fadaka jọ sinu ilé ìṣúra rẹ. O ti ní àníkún ọrọ̀ nítorí ọgbọ́n rẹ ninu òwò ṣíṣe, ìgbéraga sì ti kún ọkàn rẹ nítorí ọrọ̀ rẹ.’
Kà ISIKIẸLI 28
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ISIKIẸLI 28:1-5
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò