Esek 28:1-5

Esek 28:1-5 YBCV

Ọ̀RỌ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe, Ọmọ enia, sọ fun ọmọ-alade Tire pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitori ti ọkàn rẹ gbe soke, ati ti iwọ si wipe, Ọlọrun li emi, emi joko ni ibujoko Ọlọrun, larin okun; ṣugbọn enia ni iwọ, iwọ kì isi ṣe Ọlọrun, bi o tilẹ gbe ọkàn rẹ soke bi ọkàn Ọlọrun. Wo o, iwọ sa gbọn ju Danieli lọ; kò si si ohun ikọ̀kọ ti o le fi ara sin fun ọ. Ọgbọ́n rẹ ati oye rẹ li o fi ni ọrọ̀, o si ti ni wura ati fadáka sinu iṣura rẹ: Nipa ọgbọ́n rẹ nla ati nipa òwo rẹ li o ti fi sọ ọrọ̀ rẹ di púpọ, ọkàn rẹ si gbe soke nitori ọrọ̀ rẹ.