O. Daf 118:15-24

O. Daf 118:15-24 YBCV

Ìró ayọ̀ ati ti ìṣẹ́gun mbẹ ninu agọ awọn olododo; ọwọ ọtún Oluwa li a gbega: ọwọ ọtún Oluwa nṣe agbara. Ọwọ ọtún Oluwa li a gbega: ọwọ ọtún Oluwa nṣe agbara. Emi kì yio kú, bikoṣe yiyè, ki emi ki o si ma rohin iṣẹ Oluwa. Oluwa nà mi gidigidi: ṣugbọn kò fi mi fun ikú. Ṣi ilẹkun ẹnu-ọ̀na ododo silẹ fun mi: emi o ba ibẹ wọle, emi o ma yìn Oluwa. Eyi li ẹnu-ọ̀na Oluwa, ti awọn olododo yio ba wọle. Emi o yìn ọ: nitori ti iwọ gbohùn mi, iwọ si di igbala mi. Okuta ti awọn ọ̀mọle kọ̀ silẹ li o di pataki igun ile. Lati ọdọ Oluwa li eyi: o ṣe iyanu li oju wa. Eyi li ọjọ ti Oluwa da: awa o ma yọ̀, inu wa yio si ma dùn ninu rẹ̀.