Ẹ gbọ́ orin ayọ̀ ìṣẹ́gun, ninu àgọ́ àwọn olódodo. “Ọwọ́ ọ̀tún OLUWA ti ṣe iṣẹ́ agbára ńlá. A gbé ọwọ́ ọ̀tún OLUWA ga, ọwọ́ ọ̀tún OLUWA ti ṣe iṣẹ́ agbára ńlá!” N ò ní kú, yíyè ni n óo yè, n óo sì máa fọnrere nǹkan tí OLUWA ṣe. OLUWA jẹ mí níyà pupọ, ṣugbọn kò fi mí lé ikú lọ́wọ́. Ṣí ìlẹ̀kùn òdodo fún mi, kí n lè gba ibẹ̀ wọlé, kí n sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA. Èyí ni ẹnu ọ̀nà OLUWA; àwọn olódodo yóo gba ibẹ̀ wọlé. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, nítorí pé o gbọ́ ohùn mi, o sì ti di olùgbàlà mi. Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀, ni ó di pataki igun ilé. OLUWA ló ṣe èyí; ó sì jẹ́ ohun ìyanu lójú wa. Òní ni ọjọ́ tí OLUWA dá, ẹ jẹ́ kí á máa yọ̀, kí inú wa sì máa dùn.
Kà ORIN DAFIDI 118
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ORIN DAFIDI 118:15-24
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò