Saamu 118:15-24

Saamu 118:15-24 YCB

Ohùn ayọ̀ àti ìgbàlà ń bẹ nínú àgọ́ àwọn olódodo: “Ọwọ́ ọ̀tún OLúWA ń ṣe ohun agbára! Ọwọ́ ọ̀tún OLúWA ní a gbéga; ọwọ́ ọ̀tún OLúWA ń ṣe ohun agbára!” Èmi kì yóò kú, ṣùgbọ́n èmi yóò yè, èmi yóò pòkìkí ohun tí OLúWA ṣe. OLúWA bá mi wí gidigidi, ṣùgbọ́n òun kò fi mí lé ikú lọ́wọ́. Ṣí ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà òdodo fún mi: èmi yóò bá ibẹ̀ wọlé, èmi yóò sì fi ọpẹ́ fún OLúWA. Èyí ni ìlẹ̀kùn OLúWA ibẹ̀ ni àwọn olódodo yóò bá wọlé. Èmi yóò fi ọpẹ́ fún ọ, nítorí ó dá mi lóhùn; ìwọ sì di ìgbàlà mi. Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀, ni ó di pàtàkì igun ilé; OLúWA ti ṣe èyí, ó ṣe ìyanu ní ojú wa. Èyí ni ọjọ́ tí OLúWA dá: ẹ jẹ́ kí ayọ̀ kí inú wa sì máa dùn nínú rẹ̀.