O. Daf 118

118
Adura Ọpẹ́ fún Ìṣẹ́gun
1Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa; nitoriti o ṣeun, nitoriti ãnu rẹ̀ duro lailai.
2Jẹ ki Israeli ki o wi nisisiyi pe, ãnu rẹ̀ duro lailai.
3Jẹ ki ara-ile Aaroni ki o wi nisisiyi pe, ãnu rẹ̀ duro lailai.
4Jẹ ki awọn ti o bẹ̀ru Oluwa ki o wi nisisiyi pe, ãnu rẹ̀ duro lailai.
5Mo kepè Oluwa ninu ipọnju: Oluwa si da mi lohùn ni ibi àye nla.
6Oluwa mbẹ fun mi, emi kì yio bẹ̀ru; kili enia le ṣe si mi?
7Oluwa mbẹ fun mi pẹlu awọn ti nràn mi lọwọ: nitorina li emi o ṣe ri ifẹ mi lori awọn ti o korira mi.
8O ya lati gbẹkẹle Oluwa, jù ati gbẹkẹle enia lọ.
9O ya lati gbẹkẹle Oluwa, jù ati gbẹkẹle awọn ọmọ-alade lọ.
10Gbogbo awọn orilẹ-ède yi mi ka kiri, ṣugbọn li orukọ Oluwa emi o pa wọn run.
11Nwọn yi mi ka kiri; nitõtọ, nwọn yi mi ka kiri, ṣugbọn li orukọ Oluwa emi o pa wọn run.
12Nwọn yi mi ka kiri bi oyin; a si pa wọn bi iná ẹgún: li orukọ Oluwa emi o sa pa wọn run.
13Iwọ tì mi gidigidi ki emi ki o le ṣubu; ṣugbọn Oluwa ràn mi lọwọ.
14Oluwa li agbara ati orin mi, o si di igbala mi.
15Ìró ayọ̀ ati ti ìṣẹ́gun mbẹ ninu agọ awọn olododo; ọwọ ọtún Oluwa li a gbega: ọwọ ọtún Oluwa nṣe agbara.
16Ọwọ ọtún Oluwa li a gbega: ọwọ ọtún Oluwa nṣe agbara.
17Emi kì yio kú, bikoṣe yiyè, ki emi ki o si ma rohin iṣẹ Oluwa.
18Oluwa nà mi gidigidi: ṣugbọn kò fi mi fun ikú.
19Ṣi ilẹkun ẹnu-ọ̀na ododo silẹ fun mi: emi o ba ibẹ wọle, emi o ma yìn Oluwa.
20Eyi li ẹnu-ọ̀na Oluwa, ti awọn olododo yio ba wọle.
21Emi o yìn ọ: nitori ti iwọ gbohùn mi, iwọ si di igbala mi.
22Okuta ti awọn ọ̀mọle kọ̀ silẹ li o di pataki igun ile.
23Lati ọdọ Oluwa li eyi: o ṣe iyanu li oju wa.
24Eyi li ọjọ ti Oluwa da: awa o ma yọ̀, inu wa yio si ma dùn ninu rẹ̀.
25Ṣe igbala nisisiyi, emi mbẹ ọ, Oluwa: Oluwa emi bẹ ọ, rán alafia.
26Olubukún li ẹniti o mbọ̀ wá li orukọ Oluwa: awa ti fi ibukún fun ọ lati ile Oluwa wá.
27Ọlọrun li Oluwa, ti o ti fi imọlẹ hàn fun wa: ẹ fi okùn di ẹbọ na mọ́ iwo pẹpẹ na.
28Iwọ li Ọlọrun mi, emi o si ma yìn ọ, iwọ li Ọlọrun mi, emi o mã gbé ọ ga.
29Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa; nitori ti o ṣeun: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 118: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa