Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa; nitoriti o ṣeun, nitoriti ãnu rẹ̀ duro lailai. Jẹ ki Israeli ki o wi nisisiyi pe, ãnu rẹ̀ duro lailai. Jẹ ki ara-ile Aaroni ki o wi nisisiyi pe, ãnu rẹ̀ duro lailai. Jẹ ki awọn ti o bẹ̀ru Oluwa ki o wi nisisiyi pe, ãnu rẹ̀ duro lailai. Mo kepè Oluwa ninu ipọnju: Oluwa si da mi lohùn ni ibi àye nla. Oluwa mbẹ fun mi, emi kì yio bẹ̀ru; kili enia le ṣe si mi? Oluwa mbẹ fun mi pẹlu awọn ti nràn mi lọwọ: nitorina li emi o ṣe ri ifẹ mi lori awọn ti o korira mi. O ya lati gbẹkẹle Oluwa, jù ati gbẹkẹle enia lọ. O ya lati gbẹkẹle Oluwa, jù ati gbẹkẹle awọn ọmọ-alade lọ. Gbogbo awọn orilẹ-ède yi mi ka kiri, ṣugbọn li orukọ Oluwa emi o pa wọn run. Nwọn yi mi ka kiri; nitõtọ, nwọn yi mi ka kiri, ṣugbọn li orukọ Oluwa emi o pa wọn run. Nwọn yi mi ka kiri bi oyin; a si pa wọn bi iná ẹgún: li orukọ Oluwa emi o sa pa wọn run. Iwọ tì mi gidigidi ki emi ki o le ṣubu; ṣugbọn Oluwa ràn mi lọwọ. Oluwa li agbara ati orin mi, o si di igbala mi. Ìró ayọ̀ ati ti ìṣẹ́gun mbẹ ninu agọ awọn olododo; ọwọ ọtún Oluwa li a gbega: ọwọ ọtún Oluwa nṣe agbara. Ọwọ ọtún Oluwa li a gbega: ọwọ ọtún Oluwa nṣe agbara. Emi kì yio kú, bikoṣe yiyè, ki emi ki o si ma rohin iṣẹ Oluwa. Oluwa nà mi gidigidi: ṣugbọn kò fi mi fun ikú.
Kà O. Daf 118
Feti si O. Daf 118
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 118:1-18
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò