O. Daf 118:1-18

O. Daf 118:1-18 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Jẹ́ kí Israẹli wí pé, “Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.” Kí àwọn ará ilé Aaroni wí pé, “Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.” Kí àwọn tí ó bẹ̀rù OLUWA wí pé, “Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.” Ninu ìpọ́njú, mo ké pe OLUWA, ó dá mi lóhùn, ó sì tú mi sílẹ̀. Nígbà tí OLUWA wà pẹlu mi, ẹ̀rù kò bà mí. Kí ni eniyan lè fi mí ṣe? OLUWA wà pẹlu mi láti ràn mí lọ́wọ́, nítorí náà, n óo wo àwọn tí wọ́n kórìíra mi pẹlu ayọ̀ ìṣẹ́gun. Ó sàn láti sá di OLUWA, ju ati gbẹ́kẹ̀lé eniyan lọ. Ó sàn láti sá di OLUWA, ju ati gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìjòyè. Gbogbo orílẹ̀-èdè dòòyì ká mi, ṣugbọn ní orúkọ OLUWA, mo pa wọ́n run! Wọ́n yí mi ká, àní, wọ́n dòòyì ká mi, ṣugbọn ni orúkọ OLUWA, mo pa wọ́n run! Wọ́n ṣùrù bò mí bí oyin, ṣugbọn kíá ni wọ́n kú bí iná ìṣẹ́pẹ́; ní orúkọ OLUWA, mo pa wọ́n run. Wọ́n gbógun tì mí gidigidi, tóbẹ́ẹ̀ tí mo fẹ́rẹ̀ ṣubú, ṣugbọn OLUWA ràn mí lọ́wọ́. OLUWA ni agbára ati orin mi, ó ti di olùgbàlà mi. Ẹ gbọ́ orin ayọ̀ ìṣẹ́gun, ninu àgọ́ àwọn olódodo. “Ọwọ́ ọ̀tún OLUWA ti ṣe iṣẹ́ agbára ńlá. A gbé ọwọ́ ọ̀tún OLUWA ga, ọwọ́ ọ̀tún OLUWA ti ṣe iṣẹ́ agbára ńlá!” N ò ní kú, yíyè ni n óo yè, n óo sì máa fọnrere nǹkan tí OLUWA ṣe. OLUWA jẹ mí níyà pupọ, ṣugbọn kò fi mí lé ikú lọ́wọ́.

O. Daf 118:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ẹ fi ọpẹ́ fún OLúWA, nítorí tí ó dára; àánú rẹ̀ dúró láéláé. Jẹ́ kí Israẹli wí pé: “Àánú rẹ̀ dúró láéláé”. Jẹ́ kí ilé Aaroni wí pé: “Àánú rẹ̀ dúró láéláé”. Jẹ́ kí àwọn tí ó bẹ̀rù OLúWA wí pé: “Àánú rẹ̀ dúró láéláé.” Nínú ìrora mi, mo sọkún sí OLúWA, ó sì dá mi lóhùn nípa pé ó tú mi sílẹ̀. OLúWA ń bẹ fún èmi; èmi kì yóò bẹ̀rù. Kí ni ènìyàn lè ṣe sí mi? OLúWA ń bẹ fún mi; òun ni olùrànlọ́wọ́ mi Nítorí náà ni èmi ó ṣe rí ìṣẹ́gun mi lórí àwọn tí ó kórìíra mi. Ó dára láti máa gbẹ́kẹ̀lé OLúWA ju àti gbẹ́kẹ̀lé ènìyàn lọ. Ó dára láti máa gbẹ́kẹ̀lé OLúWA ju à ti gbẹ́kẹ̀lé àwọn ọmọ-aládé lọ. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yí mi káàkiri, ṣùgbọ́n ní orúkọ OLúWA èmi gé wọn kúrò Wọ́n yí mi káàkiri ní gbogbo ẹ̀gbẹ́, ṣùgbọ́n ní orúkọ OLúWA èmi gé wọn dànù Wọ́n gbá yìn ìn yí mi ká bí oyin, ṣùgbọ́n wọ́n kú kíákíá bí iná ẹ̀gún; ní orúkọ OLúWA èmi ké wọn dànù. Ìwọ tì mí gidigidi kí n lè ṣubú, ṣùgbọ́n OLúWA ràn mí lọ́wọ́. OLúWA ni agbára àti orin mi; ó sì di ìgbàlà mi. Ohùn ayọ̀ àti ìgbàlà ń bẹ nínú àgọ́ àwọn olódodo: “Ọwọ́ ọ̀tún OLúWA ń ṣe ohun agbára! Ọwọ́ ọ̀tún OLúWA ní a gbéga; ọwọ́ ọ̀tún OLúWA ń ṣe ohun agbára!” Èmi kì yóò kú, ṣùgbọ́n èmi yóò yè, èmi yóò pòkìkí ohun tí OLúWA ṣe. OLúWA bá mi wí gidigidi, ṣùgbọ́n òun kò fi mí lé ikú lọ́wọ́.