Owe 16:1-16

Owe 16:1-16 YBCV

IMURA aiya, ti enia ni, ṣugbọn lati ọdọ Oluwa ni idadùn ahọn. Gbogbo ọ̀na enia li o mọ́ li oju ara rẹ̀; ṣugbọn Oluwa li o ndiwọ̀n ọkàn. Kó iṣẹ rẹ le Oluwa lọwọ, a o si fi idi ìro-inu rẹ kalẹ. Oluwa ti ṣe ohun gbogbo fun ipinnu rẹ̀: nitõtọ, awọn enia buburu fun ọjọ ibi. Olukulùku enia ti o gberaga li aiya, irira ni loju Oluwa: bi a tilẹ fi ọwọ so ọwọ, kì yio wà laijiya. Nipa ãnu ati otitọ a bò ẹ̀ṣẹ mọlẹ; ati nipa ibẹ̀ru Oluwa, enia a kuro ninu ibi. Nigbati ọ̀na enia ba wù Oluwa, On a mu awọn ọtá rẹ̀ pãpa wà pẹlu rẹ̀ li alafia. Diẹ pẹlu ododo, o san jù ọrọ̀ nla lọ laisi ẹtọ́. Aiya enia ni ngbìmọ ọ̀na rẹ̀, ṣugbọn Oluwa li o ntọ́ itẹlẹ rẹ̀. Ọrọ isọtẹlẹ mbẹ li ète ọba: ẹnu rẹ̀ kì iṣẹ̀ ni idajọ. Iwọn ati òṣuwọn otitọ ni ti Oluwa: gbogbo okuta-ìwọn àpo, iṣẹ rẹ̀ ni. Irira ni fun awọn ọba lati ṣe buburu: nitoripe nipa ododo li a ti fi idi itẹ́ kalẹ. Ete ododo ni didùn-inu awọn ọba: nwọn si fẹ ẹniti nsọ̀rọ titọ. Ibinu ọba dabi iranṣẹ ikú: ṣugbọn ọlọgbọ́n enia ni yio tù u. Ni imọlẹ oju ọba ni ìye; ojurere rẹ̀ si dabi awọsanma òjo arọkuro. Lati ni ọgbọ́n, melomelo li o san jù wura lọ; ati lati ni oye, melomelo li o dara jù fadaka lọ.