Èrò ọkàn ni ti eniyan ṣugbọn OLUWA ló ni ìdáhùn. Gbogbo ọ̀nà eniyan ni ó mọ́ lójú ara rẹ̀, ṣugbọn OLUWA ló rí ọkàn. Fi gbogbo àdáwọ́lé rẹ lé OLUWA lọ́wọ́, èrò ọkàn rẹ yóo sì yọrí sí rere. OLUWA a máa jẹ́ kí ohun gbogbo yọrí sí bí ó bá ti fẹ́, ó dá eniyan burúkú fún ọjọ́ ìyọnu. OLUWA kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ agbéraga, dájúdájú kò ní lọ láìjìyà. Àánú ati òtítọ́ a máa ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀, ìbẹ̀rù OLUWA a sì máa mú ibi kúrò. Bí ọ̀nà eniyan bá tẹ́ OLUWA lọ́rùn, a máa mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ pàápàá bá a gbé pẹlu alaafia. Ìwọ̀nba ọrọ̀ pẹlu òdodo, sàn ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ tí a kójọ lọ́nà èrú lọ. Eniyan lè jókòó kí ó ṣètò ìgbésẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn OLUWA níí tọ́ ìṣísẹ̀ ẹni. Pẹlu ìmísí Ọlọrun ni ọba fi ń sọ̀rọ̀, ìdájọ́ aiṣododo kò gbọdọ̀ ti ẹnu rẹ̀ jáde. Ti OLUWA ni òṣùnwọ̀n pípé, iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo ohun tí à ń wọ̀n. Àwọn ọba kórìíra ibi ṣíṣe, nítorí nípa òdodo ni a fìdí ìjọba múlẹ̀. Inú ọba a máa dùn sí olódodo, ọba sì máa ń fẹ́ràn àwọn tí ń sọ òtítọ́. Iranṣẹ ikú ni ibinu ọba, ọlọ́gbọ́n eniyan níí tù ú lójú. Ìyè wà ninu ojurere ọba, ojurere rẹ̀ sì dàbí ṣíṣú òjò ní àkókò òjò àkọ́rọ̀. Ó sàn kí eniyan ní òye ju kí ó ní wúrà lọ, ó sì sàn kí eniyan yan ìmọ̀ ju kí ó yan fadaka lọ.
Kà ÌWÉ ÒWE 16
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ÌWÉ ÒWE 16:1-16
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò