Owe 16

16
1IMURA aiya, ti enia ni, ṣugbọn lati ọdọ Oluwa ni idadùn ahọn.
2Gbogbo ọ̀na enia li o mọ́ li oju ara rẹ̀; ṣugbọn Oluwa li o ndiwọ̀n ọkàn.
3Kó iṣẹ rẹ le Oluwa lọwọ, a o si fi idi ìro-inu rẹ kalẹ.
4Oluwa ti ṣe ohun gbogbo fun ipinnu rẹ̀: nitõtọ, awọn enia buburu fun ọjọ ibi.
5Olukulùku enia ti o gberaga li aiya, irira ni loju Oluwa: bi a tilẹ fi ọwọ so ọwọ, kì yio wà laijiya.
6Nipa ãnu ati otitọ a bò ẹ̀ṣẹ mọlẹ; ati nipa ibẹ̀ru Oluwa, enia a kuro ninu ibi.
7Nigbati ọ̀na enia ba wù Oluwa, On a mu awọn ọtá rẹ̀ pãpa wà pẹlu rẹ̀ li alafia.
8Diẹ pẹlu ododo, o san jù ọrọ̀ nla lọ laisi ẹtọ́.
9Aiya enia ni ngbìmọ ọ̀na rẹ̀, ṣugbọn Oluwa li o ntọ́ itẹlẹ rẹ̀.
10Ọrọ isọtẹlẹ mbẹ li ète ọba: ẹnu rẹ̀ kì iṣẹ̀ ni idajọ.
11Iwọn ati òṣuwọn otitọ ni ti Oluwa: gbogbo okuta-ìwọn àpo, iṣẹ rẹ̀ ni.
12Irira ni fun awọn ọba lati ṣe buburu: nitoripe nipa ododo li a ti fi idi itẹ́ kalẹ.
13Ete ododo ni didùn-inu awọn ọba: nwọn si fẹ ẹniti nsọ̀rọ titọ.
14Ibinu ọba dabi iranṣẹ ikú: ṣugbọn ọlọgbọ́n enia ni yio tù u.
15Ni imọlẹ oju ọba ni ìye; ojurere rẹ̀ si dabi awọsanma òjo arọkuro.
16Lati ni ọgbọ́n, melomelo li o san jù wura lọ; ati lati ni oye, melomelo li o dara jù fadaka lọ.
17Òpopo-ọ̀na awọn aduro-ṣinṣin ni ati kuro ninu ibi: ẹniti o pa ọ̀na rẹ̀ mọ́, o pa ọkàn rẹ̀ mọ́.
18Igberaga ni iṣaju iparun, agidi ọkàn ni iṣaju iṣubu.
19O san lati ṣe onirẹlẹ ọkàn pẹlu awọn talaka, jù ati ba awọn agberaga pin ikógun.
20Ẹniti o fi oye ṣe ọ̀ran yio ri ire; ẹniti o si gbẹkẹ le Oluwa, ibukún ni fun u.
21Ọlọgbọ́n aiya li a o pè li amoye: didùn-ète a si ma mu ẹkọ́ pọ̀.
22Oye li orisun ìye fun ẹniti o ni i: ṣugbọn ẹkọ́ aṣiwère ni iwère.
23Aiya ọlọgbọ́n mu ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ gbọ́n, o si mu ẹkọ́ pọ̀ li ète rẹ̀.
24Ọrọ didùn dabi afara oyin, o dùn mọ ọkàn, o si ṣe ilera fun egungun.
25Ọ̀na kan wà ti o dabi ẹnipe o dara fun enia, ṣugbọn opin rẹ̀ li ọ̀na ikú.
26Ọkàn ti o nṣiṣẹ, o nṣiṣẹ fun ara rẹ̀; nitoripe ẹnu ara rẹ̀ li o nsún u ṣe e.
27Enia-buburu hù ìwa-ibi jade, ati li ète rẹ̀ bi ẹnipe iná jijo li o wà nibẹ.
28Alayidayida enia dá ìja silẹ: asọ̀rọkẹlẹ yà awọn ọrẹ́ ni ipa.
29Ẹni ìwa-agbara tàn aladugbo rẹ̀, a si mu u lọ si ipa-ọ̀na ti kò dara.
30On a di oju rẹ̀ lati gbèro ohun ayidayida: o ká ète rẹ̀ sinu, o pari ohun buburu.
31Ade ogo li ori ewú, bi a ba ri i li ọ̀na ododo.
32Ẹniti o lọra ati binu, o san jù alagbara lọ; ẹniti o si ṣe akoso ẹmi rẹ̀, o jù ẹniti o ṣẹgun ilu lọ.
33A ṣẹ́ keke dà si iṣẹpo aṣọ; ṣugbọn gbogbo idajọ rẹ̀ lọwọ Oluwa ni.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Owe 16: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa