Owe 17

17
1OKELE gbigbẹ, ti on ti alafia, o san jù ile ti o kún fun ẹran-pipa ti on ti ìja.
2Ọlọgbọ́n iranṣẹ yio ṣe olori ọmọ ti nhùwa itiju, yio si pin ogún lãrin awọn arakunrin.
3Koro ni fun fadaka, ati ileru fun wura: bẹ̃li Oluwa ndan aiya wò.
4Oluṣe buburu fetisi ète eke; ẹni-eké a si ma kiyesi ọ̀rọ ahọn buburu.
5Ẹnikẹni ti o ba sín olupọnju jẹ, o gàn Ẹlẹda rẹ̀: ẹniti o ba si nyọ̀ si wahala kì yio wà li aijiya.
6Ọmọ ọmọ li ade arugbo: ogo awọn ọmọ si ni baba wọn.
7Ọ̀rọ daradara kò yẹ fun aṣiwère; bẹ̃li ète eke kò yẹ fun ọmọ-alade.
8Okuta iyebiye jẹ ẹ̀bun li oju ẹniti o ni i; nibikibi ti o yi si, a ṣe rere.
9Ẹniti o bò ẹ̀ṣẹ mọlẹ, o nwá ifẹ; ṣugbọn ẹniti o tun ọ̀ran hú silẹ, o yà ọrẹ́ nipa.
10Ibawi wọ̀ inu ọlọgbọ́n jù ọgọrun paṣan lọ ninu aṣiwère.
11Ẹni-ọ̀tẹ a ma wá kiki ibi kiri; nitorina iranṣẹ ìka li a o ran si i.
12O yá ki ẹranko beari ti a kó li ọmọ ki o pade enia, jù aṣiwère lọ ninu wère rẹ̀.
13Ẹnikẹni ti o ba fi ibi san ire, ibi kì yio kuro ninu ile rẹ̀.
14Ẹniti o daju fun omi dabi olupilẹṣẹ ìja; nitorina fi ìja silẹ ki o to di nla.
15Ẹniti o da enia buburu lare, ati ẹniti o da olododo lẹbi, ani awọn mejeji irira ni loju Oluwa.
16Nitori kini iye owo yio ṣe wà lọwọ aṣiwère lati rà ọgbọ́n, sa wò o, kò ni oye?
17Ọrẹ́ a ma fẹni nigbagbogbo, ṣugbọn arakunrin li a bi fun ìgba ipọnju.
18Enia ti oye kù fun, a ṣe onigbọwọ, a si fi ara sọfà niwaju ọrẹ́ rẹ̀.
19Ẹniti o fẹ ìja, o fẹ ẹ̀ṣẹ; ẹniti o kọ́ ẹnu-ọ̀na rẹ̀ ga, o nwá iparun.
20Ẹniti o ni ayidayida ọkàn kì yio ri ire: ati ẹniti o ni ahọn ọ̀rọ-meji, a bọ sinu ibi.
21Ẹniti o bi aṣiwère, o bi i si ibinujẹ rẹ̀; baba aṣiwère kò si li ayọ̀.
22Inu-didùn mu imularada rere wá: ṣugbọn ibinujẹ ọkàn mu egungun gbẹ.
23Enia buburu mu ẹ̀bun lati iṣẹpo-aṣọ lati yi ọ̀na idajọ pada.
24Ọgbọ́n wà niwaju ẹniti o moye; ṣugbọn oju aṣiwère mbẹ li opin ilẹ̀-aiye.
25Aṣiwère ọmọ ni ibinujẹ baba rẹ̀, ati kikoro ọkàn fun iya ti o bi i.
26Pẹlupẹlu kò dara ki a ṣẹ́ olotitọ ni iṣẹ́, tabi ki a lu ọmọ-alade nitori iṣedẽde.
27Ẹniti o ni ìmọ, a ṣẹ́ ọ̀rọ rẹ̀ kù: ọlọkàn tutu si li amoye enia.
28Lõtọ, aṣiwère, nigbati o ba pa ẹnu rẹ̀ mọ́, a kà a si ọlọgbọ́n; ẹniti o ba pa ẹnu rẹ̀ mọ́ si li amoye.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Owe 17: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa