Deu 2:1-7

Deu 2:1-7 YBCV

NIGBANA li awa pada, awa si mú ọ̀na wa pọ̀n lọ si aginjù li ọ̀na Okun Pupa, bi OLUWA ti sọ fun mi: awa si yi òke Seiri ká li ọjọ́ pupọ̀. OLUWA si sọ fun mi pe, Ẹnyin ti yi òke yi ká pẹ to: ẹ pada si ìha ariwa. Ki iwọ ki o si fi aṣẹ fun awọn enia, pe, Ẹnyin o là ẹkùn awọn arakunrin nyin kọja, awọn ọmọ Esau ti ngbé Seiri; ẹ̀ru nyin yio bà wọn: nitorina ẹ ṣọra nyin gidigidi: Ẹ máṣe bá wọn jà; nitoripe emi ki yio fun nyin ninu ilẹ wọn, ani to bi ẹsẹ̀ kan: nitoriti mo ti fi òke Seiri fun Esau ni iní. Owo ni ki ẹnyin fi rà onjẹ lọwọ wọn, ti ẹnyin o jẹ; owo ni ki ẹnyin si fi rà omi lọwọ wọn pẹlu, ti ẹnyin o mu. Nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ ti bukún ọ ninu iṣẹ ọwọ́ rẹ gbogbo: o ti mọ̀ ìrin rẹ li aginjù nla yi: li ogoji ọdún yi OLUWA Ọlọrun rẹ ti mbẹ pẹlu rẹ; ọdá ohun kan kò dá ọ.