DIUTARONOMI 2:1-7

DIUTARONOMI 2:1-7 YCE

“Nígbà tí ó yá, a pada sinu aṣálẹ̀ ní ọ̀nà Òkun Pupa, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún mi; a sì rìn káàkiri lórí òkè Seiri fún ọpọlọpọ ọjọ́. “OLUWA bá wí fún mi pé, ‘Ìrìn tí ẹ rìn káàkiri ní agbègbè olókè yìí tó gẹ́ẹ́; ẹ yipada sí apá àríwá.’ OLUWA ní kí n pàṣẹ pé, ‘Ilẹ̀ tí ẹ óo là kọjá yìí jẹ́ ilẹ̀ àwọn ọmọ Esau, àwọn arakunrin yín, tí wọn ń gbé òkè Seiri. Ẹ̀rù yín yóo máa bà wọ́n, nítorí náà, ẹ ṣọ́ra gidigidi; ẹ má bá wọn jà, nítorí n kò ní fun yín ní ilẹ̀ wọn, bí ó ti wù kí ó kéré tó. Mo ti fi gbogbo ilẹ̀ Edomu ní òkè Seiri fún arọmọdọmọ Esau, gẹ́gẹ́ bí ìní wọn. Ẹ óo ra oúnjẹ jẹ lọ́wọ́ wọn, ẹ óo sì ra omi mu lọ́wọ́ wọn.’ “Ẹ ranti bí OLUWA Ọlọrun yín ti bukun yín ninu gbogbo ohun tí ẹ dáwọ́lé, ó sì ti tọ́jú yín ní gbogbo ìgbà tí ẹ̀ ń rìn kiri ninu aṣálẹ̀ ńláńlá yìí. Ó ti wà pẹlu yín láti ogoji ọdún sẹ́yìn wá, ohunkohun kò sì jẹ yín níyà.