Deu 2:1-7
Deu 2:1-7 Yoruba Bible (YCE)
“Nígbà tí ó yá, a pada sinu aṣálẹ̀ ní ọ̀nà Òkun Pupa, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún mi; a sì rìn káàkiri lórí òkè Seiri fún ọpọlọpọ ọjọ́. “OLUWA bá wí fún mi pé, ‘Ìrìn tí ẹ rìn káàkiri ní agbègbè olókè yìí tó gẹ́ẹ́; ẹ yipada sí apá àríwá.’ OLUWA ní kí n pàṣẹ pé, ‘Ilẹ̀ tí ẹ óo là kọjá yìí jẹ́ ilẹ̀ àwọn ọmọ Esau, àwọn arakunrin yín, tí wọn ń gbé òkè Seiri. Ẹ̀rù yín yóo máa bà wọ́n, nítorí náà, ẹ ṣọ́ra gidigidi; ẹ má bá wọn jà, nítorí n kò ní fun yín ní ilẹ̀ wọn, bí ó ti wù kí ó kéré tó. Mo ti fi gbogbo ilẹ̀ Edomu ní òkè Seiri fún arọmọdọmọ Esau, gẹ́gẹ́ bí ìní wọn. Ẹ óo ra oúnjẹ jẹ lọ́wọ́ wọn, ẹ óo sì ra omi mu lọ́wọ́ wọn.’ “Ẹ ranti bí OLUWA Ọlọrun yín ti bukun yín ninu gbogbo ohun tí ẹ dáwọ́lé, ó sì ti tọ́jú yín ní gbogbo ìgbà tí ẹ̀ ń rìn kiri ninu aṣálẹ̀ ńláńlá yìí. Ó ti wà pẹlu yín láti ogoji ọdún sẹ́yìn wá, ohunkohun kò sì jẹ yín níyà.
Deu 2:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni a yípadà, tí a sì mú ọ̀nà wa pọ̀n lọ sí aginjù, a gba ọ̀nà Òkun pupa, bí OLúWA ti darí mi. Ìgbà pípẹ́ ni a fi ń rìn kiri yíká agbègbè àwọn ìlú olókè Seiri. Nígbà náà ni OLúWA sọ fún mi pé, “Ẹ ti rìn yí agbègbè ilẹ̀ olókè yìí pẹ́ tó, nísinsin yìí, ẹ yípadà sí ìhà àríwá. Fún àwọn ènìyàn náà ní àwọn òfin wọ̀nyí: ‘Ẹ ti fẹ́ la ilẹ̀ àwọn arákùnrin yín kọjá, àwọn ọmọ Esau; àwọn ará Edomu tí ń gbé ní Seiri. Ẹ̀rù yín yóò bà wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ ṣọ́ra gidigidi. Ẹ má ṣe wá wọn níjà torí pé èmi kò ní fún un yín ní èyíkéyìí nínú ilẹ̀ wọn. Bí ó ti wù kí ó kéré mọ èmi kò ní fún un yín. Mo ti fi ilẹ̀ òkè Seiri fún Esau gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀. Ẹ san owó oúnjẹ tí ẹ bá jẹ fún wọn àti omi tí ẹ bá mu.’ ” OLúWA Ọlọ́run yín ti bùkún un yín nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín. Ó ti mójútó ìrìnàjò yín nínú aginjù ńlá yìí. OLúWA Ọlọ́run yín wà pẹ̀lú u yín ní ogójì ọdún wọ̀nyí, dé bi pé ẹ̀yin kò ṣaláìní ohunkóhun.
Deu 2:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBANA li awa pada, awa si mú ọ̀na wa pọ̀n lọ si aginjù li ọ̀na Okun Pupa, bi OLUWA ti sọ fun mi: awa si yi òke Seiri ká li ọjọ́ pupọ̀. OLUWA si sọ fun mi pe, Ẹnyin ti yi òke yi ká pẹ to: ẹ pada si ìha ariwa. Ki iwọ ki o si fi aṣẹ fun awọn enia, pe, Ẹnyin o là ẹkùn awọn arakunrin nyin kọja, awọn ọmọ Esau ti ngbé Seiri; ẹ̀ru nyin yio bà wọn: nitorina ẹ ṣọra nyin gidigidi: Ẹ máṣe bá wọn jà; nitoripe emi ki yio fun nyin ninu ilẹ wọn, ani to bi ẹsẹ̀ kan: nitoriti mo ti fi òke Seiri fun Esau ni iní. Owo ni ki ẹnyin fi rà onjẹ lọwọ wọn, ti ẹnyin o jẹ; owo ni ki ẹnyin si fi rà omi lọwọ wọn pẹlu, ti ẹnyin o mu. Nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ ti bukún ọ ninu iṣẹ ọwọ́ rẹ gbogbo: o ti mọ̀ ìrin rẹ li aginjù nla yi: li ogoji ọdún yi OLUWA Ọlọrun rẹ ti mbẹ pẹlu rẹ; ọdá ohun kan kò dá ọ.