Deu 2

2
1NIGBANA li awa pada, awa si mú ọ̀na wa pọ̀n lọ si aginjù li ọ̀na Okun Pupa, bi OLUWA ti sọ fun mi: awa si yi òke Seiri ká li ọjọ́ pupọ̀.
2OLUWA si sọ fun mi pe,
3Ẹnyin ti yi òke yi ká pẹ to: ẹ pada si ìha ariwa.
4Ki iwọ ki o si fi aṣẹ fun awọn enia, pe, Ẹnyin o là ẹkùn awọn arakunrin nyin kọja, awọn ọmọ Esau ti ngbé Seiri; ẹ̀ru nyin yio bà wọn: nitorina ẹ ṣọra nyin gidigidi:
5Ẹ máṣe bá wọn jà; nitoripe emi ki yio fun nyin ninu ilẹ wọn, ani to bi ẹsẹ̀ kan: nitoriti mo ti fi òke Seiri fun Esau ni iní.
6Owo ni ki ẹnyin fi rà onjẹ lọwọ wọn, ti ẹnyin o jẹ; owo ni ki ẹnyin si fi rà omi lọwọ wọn pẹlu, ti ẹnyin o mu.
7Nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ ti bukún ọ ninu iṣẹ ọwọ́ rẹ gbogbo: o ti mọ̀ ìrin rẹ li aginjù nla yi: li ogoji ọdún yi OLUWA Ọlọrun rẹ ti mbẹ pẹlu rẹ; ọdá ohun kan kò dá ọ.
8Nigbati awa si kọja lẹba awọn arakunrin wa awọn ọmọ Esau, ti ngbé Seiri, li ọ̀na pẹtẹlẹ̀ lati Elati wá, ati lati Esion-geberi wá, awa pada, awa si kọja li ọ̀na aginjù Moabu.
9OLUWA si wi fun mi pe, Ẹ máṣe bi awọn ara Moabu ninu, bẹ̃ni ki ẹ máṣe fi ogun jà wọn: nitoripe emi ki yio fi ninu ilẹ rẹ̀ fun ọ ni iní; nitoriti mo ti fi Ari fun awọn ọmọ Loti ni iní.
10(Awọn Emimu ti ngbé inu rẹ̀ ni ìgba atijọ rí, awọn enia nla, nwọn si pọ̀, nwọn si sigbọnlẹ, bi awọn ọmọ Anaki:
11Ti a nkà kún awọn omirán, bi awọn ọmọ Anaki; ṣugbọn awọn ara Moabu a ma pè wọn ni Emimu.
12Awọn ọmọ Hori pẹlu ti ngbé Seiri rí, ṣugbọn awọn ọmọ Esau tẹle wọn, nwọn si run wọn kuro niwaju wọn, nwọn si ngbé ibẹ̀ ni ipò wọn; gẹgẹ bi Israeli ti ṣe si ilẹ-iní rẹ̀, ti OLUWA fi fun wọn.)
13Mo ní, Dide nisisiyi, ki ẹ si gòke odò Seredi. Awa si gòke odò Seredi lọ.
14Ìgba ti awa fi ti Kadeṣi-barnea wá, titi awa fi gòke odò Seredi lọ, o jẹ́ ọgbọ̀n ọdún o le mẹjọ; titi gbogbo iran awọn ologun fi run kuro ninu ibudó, bi OLUWA ti bura fun wọn.
15Pẹlupẹlu ọwọ́ OLUWA lodi si wọn nitõtọ, lati run wọn kuro ninu ibudó, titi nwọn fi run tán.
16Bẹ̃li o si ṣe, ti gbogbo awọn ologun nì run, ti nwọn si kú tán ninu awọn enia na,
17OLUWA si sọ fun mi pe,
18Iwọ o là ilẹ Ari lọ li oni, li àgbegbe Moabu:
19Nigbati iwọ ba sunmọtosi awọn ọmọ Ammoni, máṣe bi wọn ninu, bẹ̃ni ki o máṣe bá wọn jà: nitoripe emi ki yio fi ninu ilẹ awọn ọmọ Ammoni fun ọ ni iní: nitoriti mo ti fi i fun awọn ọmọ Loti ni iní.
20(A si kà eyinì pẹlu si ilẹ awọn omirán; awọn omirán ti ngbé inu rẹ̀ rí; awọn ọmọ Ammoni a si ma pè wọn ni Samsummimu.
21Awọn enia nla, ti nwọn si pọ̀, nwọn si sigbọnlẹ, bi awọn ọmọ Anaki; ṣugbọn OLUWA run wọn niwaju wọn; nwọn si tẹle wọn, nwọn si ngbé ibẹ̀ ni ipò wọn;
22Bi o ti ṣe fun awọn ọmọ Esau, ti ngbé Seiri, nigbati o run awọn ọmọ Hori kuro niwaju wọn; ti nwọn si tẹle wọn, ti nwọn si ngbé ibẹ̀ ni ipò wọn titi di oni-oloni:
23Ati awọn ọmọ Affimu ti ngbé awọn ileto, titi dé Gasa, awọn ọmọ Kaftori, ti o ti ọdọ Kaftori wá, run wọn, nwọn si ngbé ibẹ̀ ni ipò wọn.)
24Ẹ dide, ẹ mú ọ̀na nyin pọ̀n, ki ẹ si gòke odò Arnoni: wò o, emi fi Sihoni ọmọ Amori, ọba Heṣboni lé ọ lọwọ, ati ilẹ rẹ̀: bẹ̀rẹsi gbà a, ki o si bá a jagun.
25Li oni yi li emi o bẹ̀rẹsi fi ìfoya rẹ, ati ẹ̀ru rẹ sara awọn orilẹ-ède ti mbẹ ni gbogbo abẹ ọrun, ti yio gburó rẹ, ti yio si warìri, ti yio si ṣe ipàiya nitori rẹ.
Àwọn Ọmọ Israẹli Ṣẹgun Sihoni Ọba
(Num 21:21-30)
26Mo si rán onṣẹ lati aginjù Kedemotu lọ sọdọ Sihoni ọba Heṣboni pẹlu ọ̀rọ alafia, wipe,
27Jẹ ki emi ki o là ilẹ rẹ kọja lọ: ọ̀na opópo li emi o gbà, emi ki yio yà si ọtún tabi si òsi.
28Pẹlu owo ni ki iwọ ki o tà onjẹ fun mi, ki emi ki o jẹ; pẹlu owo ni ki iwọ ki o si fun mi li omi, ki emi ki o mu: kìki ki nsá fi ẹsẹ̀ mi kọja;
29Bi awọn ọmọ Esau ti ngbé Seiri, ati awọn ara Moabu ti ngbé Ari, ti ṣe si mi; titi emi o fi gòke Jordani si ilẹ ti OLUWA Ọlọrun wa fi fun wa.
30Ṣugbọn Sihoni ọba Heṣboni kò jẹ ki a kọja lẹba on: nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ mu u li àiya le, o sọ ọkàn rẹ̀ di agídi, ki o le fi on lé ọ lọwọ, bi o ti ri li oni yi.
31OLUWA si sọ fun mi pe, Wò o, emi ti bẹ̀rẹsi fi Sihoni ati ilẹ rẹ̀ fun ọ niwaju rẹ: bẹ̀rẹsi gbà a, ki iwọ ki o le ní ilẹ rẹ̀.
32Nigbana ni Sihoni jade si wa, on ati gbogbo awọn enia rẹ̀, fun ìja ni Jahasi.
33OLUWA Ọlọrun si fi i lé wa lọwọ niwaju wa; awa si kọlù u, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati gbogbo awọn enia rẹ̀.
34Awa si kó gbogbo ilu rẹ̀ ni ìgba na, awa si run awọn ọkunrin patapata, ati awọn obinrin, ati awọn ọmọ wẹ́wẹ, ni gbogbo ilu; awa kò jẹ ki ọkan ki o kù:
35Kìki ohunọ̀sin li a kó ni ikogun fun ara wa, ati ikogun ilu wọnni ti awa kó.
36Lati Aroeri lọ, ti mbẹ leti afonifoji Arnoni, ati lati ilu ni lọ ti mbẹ lẹba afonifoji nì, ani dé Gileadi, kò sí ilu kan ti o le jù fun wa: OLUWA Ọlọrun wa fi gbogbo wọn fun wa:
37Kìki ilẹ awọn ọmọ Ammoni ni iwọ kò sunmọ, tabi ibikibi lẹba odò Jaboku, tabi ilu òke wọnni, tabi ibikibi ti OLUWA Ọlọrun wa kọ̀ fun wa.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Deu 2: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀