Deu 1

1
Ìwé Karun-un Mose, tí à ń pè ní Diutaronomi
1WỌNYI li ọ̀rọ ti Mose sọ fun gbogbo Israeli ni ìha ihin Jordani li aginjù, ni pẹtẹlẹ̀ ti o kọjusi Okun Pupa, li agbedemeji Parani, ati Tofeli, ati Labani, ati Haserotu, ati Disahabu.
2Ijọ́ mọkanla ni lati Horebu wá li ọ̀na òke Seiri dé Kadeṣi-barnea.
3O si ṣe nigbati o di ogoji ọdún, li oṣù kọkanla, li ọjọ́ kini oṣù na, ni Mose sọ fun awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA ti fun u li aṣẹ fun wọn;
4Lẹhin igbati o pa Sihoni tán ọba awọn ọmọ Amori, ti o ngbé Heṣboni, ati Ogu ọba Baṣani, ti o ngbé Aṣtarotu, ni Edrei:
5Ni ìha ihin Jordani, ni ilẹ Moabu, on ni Mose bẹ̀rẹsi isọ asọye ofin yi, wipe,
6OLUWA Ọlọrun wa sọ fun wa ni Horebu, wipe, Ẹ gbé ori òke yi pẹ to:
7Ẹ yipada, ki ẹnyin si mú ọ̀na nyin pọ̀n, ki ẹ si lọ si òke awọn ọmọ Amori, ati si gbogbo àgbegbe rẹ̀, ni pẹtẹlẹ̀, li ori òke, ati li afonifoji, ati ni ìha gusù, ati leti okun, si ilẹ awọn ara Kenaani, ati si Lebanoni, dé odò nla nì, odò Euferate.
8Wò o, mo ti fi ilẹ na siwaju nyin: ẹ wọ̀ ọ lọ ki ẹ si gbà ilẹ na ti OLUWA bura fun awọn baba nyin, fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu, lati fi fun wọn ati fun irú-ọmọ wọn lẹhin wọn.
Mose Yan Àwọn Adájọ́
(Eks 18:13-27)
9Mo si sọ fun nyin ni ìgba na pe, Emi nikan kò le rù ẹrù nyin:
10OLUWA Ọlọrun nyin ti mu nyin bisi i, si kiyesi i, li oni ẹnyin dabi irawọ oju-ọrun fun ọ̀pọ.
11Ki OLUWA, Ọlọrun awọn baba nyin ki o fi kún iye nyin ni ìgba ẹgbẹrun, ki o si busi i fun nyin, bi o ti ṣe ileri fun nyin!
12Emi o ti ṣe le nikan rù inira nyin, ati ẹrù nyin, ati ìja nyin?
13Ẹ mú awọn ọkunrin ọlọgbọ́n wá, ati amoye, ati ẹniti a mọ̀ ninu awọn ẹ̀ya nyin, emi o si fi wọn jẹ olori nyin.
14Ẹnyin si da mi li ohùn, ẹ si wipe, Ohun ti iwọ sọ nì, o dara lati ṣe.
15Bẹ̃ni mo mú olori awọn ẹ̀ya nyin, awọn ọlọgbọ́n ọkunrin, ẹniti a mọ̀, mo si fi wọn jẹ olori nyin, olori ẹgbẹgbẹrun, ati olori ọrọrún, ati olori arãdọta, ati olori mẹwa-mẹwa, ati awọn olori gẹgẹ bi awọn ẹ̀ya nyin.
16Mo si fi aṣẹ lelẹ fun awọn onidajọ nyin nigbana pe, Ẹ ma gbọ́ ẹjọ́ lãrin awọn arakunrin nyin, ki ẹ si ma ṣe idajọ ododo lãrin olukuluku ati arakunrin rẹ̀, ati alejò ti mbẹ lọdọ rẹ̀.
17Ẹ kò gbọdọ ṣe ojuṣaju ni idajọ; ẹ gbọ́ ti ewe gẹgẹ bi ti àgba; ẹ kò gbọdọ bẹ̀ru oju enia; nitoripe ti Ọlọrun ni idajọ: ọ̀ran ti o ba si ṣoro fun nyin, ẹ mú u tọ̀ mi wá, emi o si gbọ́ ọ.
18Emi si fi aṣẹ ohun gbogbo ti ẹnyin o ma ṣe lelẹ fun nyin ni ìgba na.
Mose Rán Àwọn Amí láti Kadeṣi Banea Lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí
(Num 13:1-33)
19Nigbati awa si kuro ni Horebu, awa rìn gbogbo aginjù nla nì ti o ni ẹ̀ru já, ti ẹnyin ri li ọ̀na òke awọn ọmọ Amori, bi OLUWA Ọlọrun wa ti fun wa li aṣẹ; awa si wá si Kadeṣi-barnea.
20Emi si wi fun nyin pe, Ẹnyin dé òke awọn ọmọ Amori na, ti OLUWA Ọlọrun wa fi fun wa.
21Wò o, OLUWA Ọlọrun rẹ ti fi ilẹ na siwaju rẹ: gòke lọ, ki o si gbà a, bi OLUWA, Ọlọrun awọn baba rẹ ti wi fun ọ; máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki àiya máṣe fò ọ.
22Gbogbo nyin si tọ̀ mi wá, ẹ si wipe, Jẹ ki awa ki o rán enia lọ siwaju wa, ki nwọn ki o si rìn ilẹ na wò fun wa, ki nwọn ki o si mú ìhin pada tọ̀ wa wá, niti ọ̀na ti a o ba gòke lọ, ati ti ilu ti a o yọ si.
23Ọ̀rọ na si dara loju mi: mo si yàn ọkunrin mejila ninu nyin, ẹnikan ninu ẹ̀ya kan:
24Nwọn si yipada nwọn si lọ sori òke, nwọn si wá si afonifoji Eṣkolù, nwọn si rìn ilẹ na wò.
25Nwọn si mú ninu eso ilẹ na li ọwọ́ wọn, nwọn si mú u sọkalẹ wá fun wa, nwọn si mú ìhin pada wá fun wa, nwọn si wipe, Ilẹ ti OLUWA wa fi fun wa, ilẹ rere ni.
26Ṣugbọn ẹnyin kò fẹ́ gòke lọ, ẹnyin si ṣọ̀tẹ si aṣẹ OLUWA Ọlọrun nyin:
27Ẹnyin si kùn ninu agọ́ nyin, wipe, Nitoriti OLUWA korira wa, li o ṣe mú wa lati Egipti jade wá, lati fi wa lé ọwọ́ awọn ọmọ Amori, lati run wa.
28Nibo li awa o gbé gòke lọ? awọn arakunrin wa ti daiyajá wa, wipe, Awọn enia na sigbọnlẹ jù wa lọ; ilu wọn tobi a si mọdi wọn kan ọrun; pẹlupẹlu awa ri awọn ọmọ Anaki nibẹ̀.
29Nigbana ni mo wi fun nyin pe, Ẹ máṣe fòya, bẹ̃ni ki ẹ máṣe bẹ̀ru wọn.
30OLUWA Ọlọrun nyin ti nṣaju nyin, on ni yio jà fun nyin, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ṣe fun nyin ni Egipti li oju nyin;
31Ati li aginjù, nibiti iwọ ri bi OLUWA Ọlọrun rẹ ti gbé ọ, bi ọkunrin ti igbé ọmọ rẹ̀, li ọ̀na nyin gbogbo ti ẹnyin rìn, titi ẹnyin fi dé ihinyi.
32Sibẹ̀ ninu nkan yi ẹnyin kò gbà OLUWA Ọlọrun nyin gbọ́.
33Ti nlọ li ọ̀na ṣaju nyin, lati wá ibi fun nyin, ti ẹnyin o pagọ́ nyin si, ninu iná li oru, lati fi ọ̀na ti ẹnyin o gbà hàn nyin, ati ninu awọsanma li ọsán.
OLUWA Jẹ Àwọn Ọmọ Israẹli Níyà
(Num 14:20-45)
34OLUWA si gbọ́ ohùn ọ̀rọ nyin, o si binu, o si bura, wipe,
35Nitõtọ ọkan ninu awọn ọkunrin wọnyi ti iran buburu yi, ki yio ri ilẹ rere na, ti mo ti bura lati fi fun awọn baba nyin,
36Bikoṣe Kalebu ọmọ Jefunne, on ni yio ri i; on li emi o fi ilẹ na ti o tẹ̀mọlẹ fun, ati fun awọn ọmọ rẹ̀: nitoriti o tẹle OLUWA lẹhin patapata.
37OLUWA si binu si mi pẹlu nitori nyin, wipe, Iwọ pẹlu ki yio dé ibẹ̀:
38Joṣua ọmọ Nuni, ti ima duro niwaju rẹ, on ni yio dé ibẹ̀: gbà a ni iyanju; nitoripe on ni yio mu Israeli ní i.
39Ati awọn ọmọ wẹ́wẹ nyin, ti ẹnyin wipe nwọn o di ijẹ, ati awọn ọmọ nyin, ti nwọn kò mọ̀ rere tabi buburu loni yi, awọn ni o dé ibẹ̀, awọn li emi o si fi i fun, awọn ni yio si ní i.
40Ṣugbọn bi o ṣe ti nyin ni, ẹ pada, ẹ mú ọ̀na nyin pọ̀n lọ si aginjù li ọ̀na Okun Pupa.
41Nigbana li ẹ dahùn, ẹ si wi fun mi pe, Awa ti ṣẹ̀ si OLUWA, awa o gòke lọ, a o si jà, gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA Ọlọrun wa palaṣẹ fun wa. Ati olukuluku nyin dì ihamọra ogun rẹ̀, ẹnyin mura lati gùn ori òke na.
42OLUWA si wi fun mi pe, Wi fun wọn pe, Ẹ máṣe gòke lọ, bẹ̃ni ki ẹ màṣe jà; nitoriti emi kò sí lãrin nyin; ki a má ba lé nyin niwaju awọn ọtá nyin.
43Mo sọ fun nyin, ẹnyin kò si gbọ́; ẹnyin ṣọ̀tẹ si aṣẹ OLUWA, ẹnyin sì kùgbu lọ si ori òke na.
44Awọn ọmọ Amori, ti ngbé ori òke na, si jade tọ̀ nyin wá, nwọn si lepa nyin, bi oyin ti iṣe, nwọn si run nyin ni Seiri, titi dé Horma.
45Ẹnyin si pada ẹ sì sọkun niwaju OLUWA; ṣugbọn OLUWA kò gbọ́ ohùn nyin, bẹ̃ni kò fetisi nyin.
Àkókò Tí Àwọn Ọmọ Israẹli Fi Wà ninu Aṣálẹ̀
46Ẹnyin si joko ni Kadeṣi li ọjọ́ pupọ̀, gẹgẹ bi ọjọ́ ti ẹnyin joko nibẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Deu 1: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa