I. A. Ọba 18:41-44

I. A. Ọba 18:41-44 YBCV

Elijah si wi fun Ahabu pe, Goke lọ, jẹ, ki o si mu; nitori iró ọ̀pọlọpọ òjo mbẹ. Bẹ̃ni Ahabu goke lọ lati jẹ ati lati mu. Elijah si gun ori oke Karmeli lọ; o si tẹriba o si fi oju rẹ̀ si agbedemeji ẽkun rẹ̀, O si wi fun ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Goke lọ nisisiyi, ki o si wò iha okun. On si goke lọ, o si wò, o si wipe, Kò si nkan. O si wipe, Tun lọ nigba meje. O si ṣe, ni igba keje, o si wipe, Kiyesi i, awọsanmọ kekere kan dide lati inu okun, gẹgẹ bi ọwọ́ enia. On si wipe, Goke lọ, wi fun Ahabu pe, Di kẹkẹ́ rẹ, ki o si sọkalẹ, ki òjo ki o má ba da ọ duro.