ÀWỌN ỌBA KINNI 18:41-44

ÀWỌN ỌBA KINNI 18:41-44 YCE

Lẹ́yìn náà, Elija sọ fún Ahabu ọba pé, “Lọ, jẹun, kí o wá nǹkan mu, nítorí mo gbọ́ kíkù òjò.” Nígbà tí Ahabu lọ jẹun, Elija gun orí òkè Kamẹli lọ, ó wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀, ó sì ki orí bọ ààrin orúnkún rẹ̀ mejeeji. Ó sọ fún iranṣẹ rẹ̀ pé kí ó lọ wo apá ìhà òkun. Iranṣẹ náà lọ, ó sì pada wá, ó ní, òun kò rí nǹkankan. Elija sọ fún un pé, “Tún lọ ní ìgbà meje.” Ní ìgbà keje tí ó pada dé, ó ní, “Mo rí ìkùukùu kan tí ń bọ̀ láti inú òkun, ṣugbọn kò ju àtẹ́lẹwọ́ lọ.” Elija pàṣẹ fún iranṣẹ rẹ̀ pé kí ó lọ sọ fún ọba, kí ó kó sinu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, kí ó sì sọ̀kalẹ̀ pada sí ilé kí òjò má baà ká a mọ́ ibi tí ó wà.