I. A. Ọba 18:41-44
I. A. Ọba 18:41-44 Bibeli Mimọ (YBCV)
Elijah si wi fun Ahabu pe, Goke lọ, jẹ, ki o si mu; nitori iró ọ̀pọlọpọ òjo mbẹ. Bẹ̃ni Ahabu goke lọ lati jẹ ati lati mu. Elijah si gun ori oke Karmeli lọ; o si tẹriba o si fi oju rẹ̀ si agbedemeji ẽkun rẹ̀, O si wi fun ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Goke lọ nisisiyi, ki o si wò iha okun. On si goke lọ, o si wò, o si wipe, Kò si nkan. O si wipe, Tun lọ nigba meje. O si ṣe, ni igba keje, o si wipe, Kiyesi i, awọsanmọ kekere kan dide lati inu okun, gẹgẹ bi ọwọ́ enia. On si wipe, Goke lọ, wi fun Ahabu pe, Di kẹkẹ́ rẹ, ki o si sọkalẹ, ki òjo ki o má ba da ọ duro.
I. A. Ọba 18:41-44 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn náà, Elija sọ fún Ahabu ọba pé, “Lọ, jẹun, kí o wá nǹkan mu, nítorí mo gbọ́ kíkù òjò.” Nígbà tí Ahabu lọ jẹun, Elija gun orí òkè Kamẹli lọ, ó wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀, ó sì ki orí bọ ààrin orúnkún rẹ̀ mejeeji. Ó sọ fún iranṣẹ rẹ̀ pé kí ó lọ wo apá ìhà òkun. Iranṣẹ náà lọ, ó sì pada wá, ó ní, òun kò rí nǹkankan. Elija sọ fún un pé, “Tún lọ ní ìgbà meje.” Ní ìgbà keje tí ó pada dé, ó ní, “Mo rí ìkùukùu kan tí ń bọ̀ láti inú òkun, ṣugbọn kò ju àtẹ́lẹwọ́ lọ.” Elija pàṣẹ fún iranṣẹ rẹ̀ pé kí ó lọ sọ fún ọba, kí ó kó sinu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, kí ó sì sọ̀kalẹ̀ pada sí ilé kí òjò má baà ká a mọ́ ibi tí ó wà.
I. A. Ọba 18:41-44 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Elijah sì wí fún Ahabu pé, “Lọ, jẹ, kí o sì mu, nítorí ìró ọ̀pọ̀lọpọ̀ òjò ń bọ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni Ahabu gòkè lọ láti jẹ àti láti mu. Ṣùgbọ́n Elijah gun orí òkè Karmeli lọ ó sì tẹríba, ó sì fi ojú rẹ̀ sí agbede-méjì eékún rẹ̀. Ó sì wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, “Lọ, kí o sì wo ìhà Òkun, òun sì gòkè lọ, ó sì wò.” Ó sì wí pé, “Kò sí nǹkan níbẹ̀.” Ó sì wí pé, “Tún lọ nígbà méje.” Nígbà keje, ìránṣẹ́ náà sì wí pé, “Àwọsánmọ̀ kékeré kan dìde láti inú Òkun, gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ ènìyàn.” Elijah sì wí pé, “Lọ, kí o sọ fún Ahabu pé, ‘Di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ, kí o sì sọ̀kalẹ̀ lọ, kí òjò ó má ba à dá ọ dúró.’ ”