I. A. Ọba 18

18
Elija ati Àwọn Wolii Baali
1O si ṣe, lẹhin ọjọ pupọ, ọ̀rọ Oluwa tọ Elijah wá lọdun kẹta, wipe, Lọ, fi ara rẹ hàn Ahabu; emi o si rọ̀ òjo sori ilẹ.
2Elijah si lọ ifi ara rẹ̀ han Ahabu. Iyan nla si mu ni Samaria.
3Ahabu si pe Obadiah, ti iṣe olori ile rẹ̀. Njẹ Obadiah bẹ̀ru Oluwa gidigidi:
4O si ṣe, nigbati Jesebeli ke awọn woli Oluwa kuro, ni Obadiah mu ọgọrun woli, o si fi wọn pamọ li aradọta ni iho okuta; o si fi àkara pẹlu omi bọ́ wọn.
5Ahabu si wi fun Obadiah pe, Rin ilẹ lọ, si orisun omi gbogbo, ati si odò gbogbo: bọya awa le ri koriko lati gbà awọn ẹṣin ati awọn ibãka là, ki a má ba ṣòfo awọn ẹranko patapata.
6Nwọn si pin ilẹ na lãrin ara wọn, lati là a ja: Ahabu gba ọ̀na kan lọ fun ara rẹ̀, Obadiah si gba ọ̀na miran lọ fun ara rẹ̀.
7Nigbati Obadiah si wà li ọ̀na, kiyesi i, Elijah pade rẹ̀: nigbati o mọ̀ ọ, o si doju rẹ̀ bolẹ, o si wipe, Ṣé iwọ oluwa mi Elijah nìyí?
8O si da a lohùn pe, Emi ni: lọ, sọ fun oluwa rẹ pe, Wò o, Elijah mbẹ nihin.
9On si wipe, Ẹ̀ṣẹ kini mo ha dá, ti iwọ fẹ fi iranṣẹ rẹ le Ahabu lọwọ lati pa mi?
10Bi Oluwa Ọlọrun rẹ ti wà, kò si orilẹ-ède tabi ijọba kan, nibiti oluwa mi kò ranṣẹ de lati wò ọ: nigbati nwọn ba si wipe, Kò si; on a mu ki ijọba tabi orilẹ-ède na bura pe: awọn kò ri ọ.
11Nisisiyi iwọ si wipe, Lọ, sọ fun oluwa rẹ pe, Wò o, Elijah mbẹ nihin;
12Yio si ṣe bi emi o ti lọ kuro li ọdọ rẹ, Ẹmi Oluwa yio si gbe ọ lọ si ibi ti emi kò mọ̀; nigbati mo ba si de, ti mo si wi fun Ahabu, ti kò ba si ri ọ, on o pa mi: ṣugbọn emi, iranṣẹ rẹ, bẹ̀ru Oluwa lati igba ewe mi wá.
13A kò ha sọ fun oluwa mi, ohun ti mo ṣe nigbati Jesebeli pa awọn woli Oluwa, bi mo ti pa ọgọrun enia mọ ninu awọn woli Oluwa li aradọta ninu ihò-okuta, ti mo si fi àkara pẹlu omi bọ́ wọn?
14Nisisiyi, iwọ si wipe, Lọ sọ fun oluwa rẹ pe, Wò o, Elijah mbẹ nihin! on o si pa mi.
15Elijah si wipe, Bi Oluwa awọn ọmọ-ogun ti wà, niwaju ẹniti emi duro, nitõtọ, emi o fi ara mi han fun u loni yi.
16Bẹ̃ni Obadiah lọ lati pade Ahabu, o si sọ fun u: Ahabu si lọ lati pade Elijah.
17O si ṣe, bi Ahabu ti ri Elijah, Ahabu si wi fun u pe, Iwọ li ẹniti nyọ Israeli li ẹnu!
18On sì dahùn pe, Emi kò yọ Israeli li ẹnu; bikoṣe iwọ ati ile baba rẹ, ninu eyiti ẹnyin ti kọ̀ ofin Oluwa silẹ, ti iwọ si ti ntọ̀ Baalimu lẹhin.
19Nitorina, ranṣẹ nisisiyi, ki o si kó gbogbo Israeli jọ sọdọ mi si oke Karmeli ati awọn woli Baali ãdọtalenirinwo, ati awọn woli ere-oriṣa irinwo, ti njẹun ni tabili Jesebeli.
20Bẹ̃ni Ahabu ranṣẹ si gbogbo awọn ọmọ Israeli, o si kó awọn woli jọ si oke Karmeli.
21Elijah si tọ gbogbo awọn enia na wá, o si wipe, Yio ti pẹ to ti ẹnyin o ma ṣiyemeji? Bi Oluwa ba ni Ọlọrun, ẹ mã tọ̀ ọ lẹhin: ṣugbọn bi Baali ba ni ẹ mã tọ̀ ọ lẹhin! Awọn enia na kò si da a li ohùn ọ̀rọ kan.
22Elijah si wi fun awọn enia na pe, Emi, ani emi nikanṣoṣo li o kù ni woli Oluwa; ṣugbọn awọn woli Baali ãdọta-lenirinwo ọkunrin,
23Nitorina jẹ ki nwọn ki o fun wa li ẹgbọrọ akọ-malu meji; ki nwọn ki o si yàn ẹgbọrọ akọ-malu kan fun ara wọn, ki nwọn ki o si ke e, ki nwọn ki o si tò o si ori igi, ki nwọn ki o má ṣe fi iná si i: emi o si tun ẹgbọrọ akọ-malu keji ṣe, emi o si tò o sori igi, emi kì o si fi iná si i.
24Ki ẹ si kepe orukọ awọn ọlọrun nyin, emi o si kepè orukọ Oluwa: Ọlọrun na ti o ba fi iná dahùn on na li Ọlọrun. Gbogbo awọn enia na si dahùn, nwọn si wipe, O wi i re.
25Elijah si wi fun awọn woli Baali pe, Ẹ yàn ẹgbọrọ akọ-malu kan fun ara nyin, ki ẹ si tètekọ ṣe e: nitori ẹnyin pọ̀: ki ẹ si kepè orukọ awọn ọlọrun nyin, ṣugbọn ẹ máṣe fi iná si i,
26Nwọn si mu ẹgbọrọ akọ-malu na ti a fi fun wọn, nwọn si ṣe e, nwọn si kepè orukọ Baali lati owurọ titi di ọ̀sangangan wipe, Baali! da wa lohùn. Ṣugbọn kò si ohùn, bẹ̃ni kò si idahùn. Nwọn si jó yi pẹpẹ na ka, eyiti nwọn tẹ́.
27O si ṣe, li ọ̀sangangan ni Elijah fi wọn ṣe ẹlẹya o si wipe, Ẹ kigbe lohùn rara, ọlọrun sa li on; bọya o nṣe àṣaro, tabi on nlepa, tabi o re àjo, bọya o sùn, o yẹ ki a ji i.
28Nwọn si kigbe lohùn rara, nwọn si fi ọbẹ ati ọ̀kọ ya ara wọn gẹgẹ bi iṣe wọn, titi ẹ̀jẹ fi tu jade li ara wọn.
29O si ṣe, nigbati ọjọ kan atarí, nwọn si nfi were sọtẹlẹ titi di akoko irubọ aṣalẹ, kò si ohùn, bẹ̃ni kò si idahùn, tabi ẹniti o kà a si.
30Njẹ Elijah wi fun gbogbo awọn enia na pe, Ẹ sunmọ mi. Gbogbo awọn enia na si sunmọ ọ. On si tun pẹpẹ Oluwa ti o ti wo lulẹ ṣe.
31Elijah si mu okuta mejila, gẹgẹ bi iye ẹ̀ya ọmọ Jakobu, ẹniti ọ̀rọ Oluwa tọ̀ wá, wipe, Israeli li orukọ rẹ yio ma jẹ:
32Okuta wọnyi li o fi tẹ́ pẹpẹ kan li orukọ Oluwa, o si wà kòtò yi pẹpẹ na ka, ti o le gba iwọn oṣùwọn irugbin meji.
33O si to igi na daradara, o si ke ẹgbọrọ akọ-malu na, o si tò o sori igi, o si wipe, fi omi kún ikoko mẹrin, ki ẹ si tú u sori ẹbọ sisun ati sori igi na.
34O si wipe, Ṣe e nigba keji. Nwọn si ṣe e nigba keji. O si wipe, Ṣe e nigba kẹta. Nwọn si ṣe e nigba kẹta.
35Omi na si ṣàn yi pẹpẹ na ka, o si fi omi kún kòtò na pẹlu.
36O si ṣe, ni irubọ aṣalẹ, ni Elijah woli sunmọ tòsi, o si wipe, Oluwa Ọlọrun Abrahamu, Isaaki, ati Israeli, jẹ ki o di mimọ̀ loni pe, iwọ li Ọlọrun ni Israeli, emi si ni iranṣẹ rẹ, ati pe mo ṣe gbogbo nkan wọnyi nipa ọ̀rọ rẹ.
37Gbọ́ ti emi, Oluwa, gbọ́ ti emi, ki awọn enia yi ki o le mọ̀ pe, Iwọ Oluwa li Ọlọrun, ati pe, Iwọ tún yi ọkàn wọn pada.
38Nigbana ni iná Oluwa bọ́ silẹ, o si sun ẹbọsisun na ati igi, ati okuta wọnnì, ati erupẹ o si lá omi ti mbẹ ninu yàra na.
39Nigbati gbogbo awọn enia ri i, nwọn da oju wọn bolẹ: nwọn si wipe, Oluwa, on li Ọlọrun; Oluwa, on li Ọlọrun!
40Elijah si wi fun wọn pe, Ẹ mu awọn woli Baali; máṣe jẹ ki ọkan ninu wọn ki o salà. Nwọn si mu wọn: Elijah si mu wọn sọkalẹ si odò Kiṣoni, o si pa wọn nibẹ.
Ọ̀dá Parí
41Elijah si wi fun Ahabu pe, Goke lọ, jẹ, ki o si mu; nitori iró ọ̀pọlọpọ òjo mbẹ.
42Bẹ̃ni Ahabu goke lọ lati jẹ ati lati mu. Elijah si gun ori oke Karmeli lọ; o si tẹriba o si fi oju rẹ̀ si agbedemeji ẽkun rẹ̀,
43O si wi fun ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Goke lọ nisisiyi, ki o si wò iha okun. On si goke lọ, o si wò, o si wipe, Kò si nkan. O si wipe, Tun lọ nigba meje.
44O si ṣe, ni igba keje, o si wipe, Kiyesi i, awọsanmọ kekere kan dide lati inu okun, gẹgẹ bi ọwọ́ enia. On si wipe, Goke lọ, wi fun Ahabu pe, Di kẹkẹ́ rẹ, ki o si sọkalẹ, ki òjo ki o má ba da ọ duro.
45O si ṣe, nigba diẹ si i, ọrun si ṣu fun awọsanmọ on iji, òjo pupọ si rọ̀. Ahabu si gun kẹkẹ́, o si lọ si Jesreeli.
46Ọwọ́ Oluwa si mbẹ lara Elijah: o si di amure ẹ̀gbẹ rẹ̀, o si sare niwaju Ahabu titi de Jesreeli.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. A. Ọba 18: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa