ORIN DAFIDI 98

98
Ọlọrun, Ọba gbogbo Ayé
1Ẹ kọ orin titun sí OLUWA,
nítorí tí ó ti ṣe ohun ìyanu;
agbára ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ati apá mímọ́ rẹ̀ ni ó fi ṣẹgun.
2OLUWA ti sọ ìṣẹ́gun rẹ̀ di mímọ̀,
ó ti fi ìdáláre rẹ̀ hàn lójú àwọn orílẹ̀-èdè.
3Ó ranti ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, ati òtítọ́ rẹ̀
sí àwọn ọmọ Israẹli;
gbogbo ayé ti rí ìṣẹ́gun Ọlọrun wa.
4Gbogbo ayé, ẹ hó ìhó ayọ̀ sí OLUWA;
ẹ bú sí orin ayọ̀, kí ẹ sì kọ orin ìyìn.
5Ẹ fi hapu kọ orin ìyìn sí OLUWA,
àní, hapu ati ohùn orin dídùn.
6Ẹ fun fèrè ati ìwo
kí ẹ sì hó ìhó ayọ̀ níwájú OLUWA Ọba.
7Kí òkun ó hó, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀,
kí ayé hó, ati àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
8Omi òkun, ẹ pàtẹ́wọ́;
kí ẹ̀yin òkè sì fi ayọ̀ kọrin pọ̀
9níwájú OLUWA, nítorí pé ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé.
Yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé;
yóo sì fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 98: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀