ORIN DAFIDI 97

97
Ọlọrun Ọba Atóbijù
1OLUWA jọba, kí ayé ó yọ̀;
jẹ́ kí inú ogunlọ́gọ̀ erékùṣù ó dùn.
2Ìkùukùu ati òkùnkùn biribiri ni ó yí i ká;
òdodo ati ẹ̀tọ́ ni ìpìlẹ̀ ìtẹ́ rẹ̀.
3Iná ń jó lọ níwájú rẹ̀,
ó sì ń jó àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́tùn-ún lósì.
4Mànàmáná rẹ̀ tan ìmọ́lẹ̀ sí ayé,
ilẹ̀ ayé rí i, ó sì wárìrì.
5Àwọn òkè ńlá yọ́ bí ìda níwájú OLUWA,
àní, níwájú OLUWA gbogbo ayé.
6Ojú ọ̀run ń kéde òdodo rẹ̀;
gbogbo orílẹ̀-èdè sì ń wo ògo rẹ̀.
7Ojú ti gbogbo àwọn tí ń bọ oriṣa,
àwọn tí ń fi ère lásánlàsàn yangàn;
gbogbo oriṣa ní ń foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀.
8Àwọn ará Sioni gbọ́, inú wọn dùn.
Àwọn ará ìlú Juda sì ń yọ̀,
nítorí ìdájọ́ rẹ, OLUWA.
9Nítorí ìwọ OLUWA ni Ọ̀gá Ògo,
o ju gbogbo ayé lọ,
a gbé ọ ga ju gbogbo oriṣa lọ.
10Ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn OLUWA, ẹ kórìíra ibi;
OLUWA á máa dá ẹ̀mí àwọn olùfọkànsìn rẹ̀ sí,
a sì máa gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú.
11Ìmọ́lẹ̀ á máa tàn fún àwọn olódodo,
ayọ̀ sì wà fún àwọn olótìítọ́ inú.
12Ẹ máa yọ̀ ninu OLUWA, ẹ̀yin olódodo,
kí ẹ sì máa yin orúkọ mímọ́ rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 97: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀