ORIN DAFIDI 99

99
Ọlọrun Ọba Atóbijù
1OLUWA jọba, kí àwọn orílẹ̀-èdè wárìrì;
ó gúnwà lórí àwọn kerubu; kí ilẹ̀ mì tìtì.
2OLUWA tóbi ní Sioni,
ó sì jọba lórí gbogbo orílẹ̀-èdè.
3Jẹ́ kí wọ́n yin orúkọ rẹ tí ó tóbi tí ó sì lẹ́rù,
mímọ́ ni OLUWA!#Eks 25:22
4Ọba alágbára, ìwọ tí o fẹ́ràn òdodo,
o ti fi ìdí ẹ̀tọ́ múlẹ̀;
o ti dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ ati òdodo ní ilẹ̀ Jakọbu.
5Ẹ yin OLUWA, Ọlọrun wa,
ẹ jọ́sìn níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀;
mímọ́ ni OLUWA!
6Mose ati Aaroni wà lára àwọn alufaa rẹ̀;
Samuẹli pàápàá wà lára àwọn tí ń pe orúkọ rẹ̀;
wọ́n ké pe OLUWA ó sì dá wọn lóhùn.
7Ó bá wọn sọ̀rọ̀ ninu ọ̀wọ̀n ìkùukùu;
wọ́n pa òfin rẹ̀ mọ́;
wọ́n sì tẹ̀lé ìlànà tí ó fún wọn.#Eks 33:9
8OLUWA Ọlọrun wa, o dá wọn lóhùn;
Ọlọrun tíí dáríjì ni ni o jẹ́ fún wọn;
ṣugbọn ó gbẹ̀san ìwàkiwà wọn.
9Ẹ yin OLUWA, Ọlọrun wa,
kí ẹ sì jọ́sìn níbi òkè mímọ́ rẹ̀;
nítorí pé mímọ́ ni OLUWA Ọlọrun wa.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 99: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀