ORIN DAFIDI 57
57
Adura Ìrànlọ́wọ́#1Sam 22:1; 24:3
1Ṣàánú mi, Ọlọrun, ṣàánú mi,
nítorí ìwọ ni ààbò mi;
abẹ́ òjìji apá rẹ ni n óo fi ṣe ààbò mi,
títí gbogbo àjálù wọnyi yóo fi kọjá.
2Mo ké pe Ọlọrun Ọ̀gá Ògo,
Ọlọrun tí ó mú èrò rẹ̀ ṣẹ fún mi.
3Yóo ranṣẹ láti ọ̀run wá, yóo gbà mí là,
yóo dójú ti àwọn tí ń lépa ẹ̀mí mi.
Ọlọrun yóo fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀
ati òtítọ́ rẹ̀ hàn!
4Ààrin àwọn kinniun ni mo dùbúlẹ̀ sí,
àwọn tí ń jẹ eniyan ní ìjẹ ìwọ̀ra;
eyín wọn dàbí ọ̀kọ̀ ati ọfà,
ahọ́n wọn sì dàbí idà.
5Gbé ara rẹ ga, Ọlọrun,
gbé ara rẹ ga ju ọ̀run lọ,
kí ògo rẹ sì tàn ká gbogbo ayé.
6Wọ́n dẹ àwọ̀n sí ojú ọ̀nà mi;
ìpọ́njú dorí mi kodò.
Wọ́n gbẹ́ kòtò sílẹ̀ dè mí,
ṣugbọn àwọn fúnra wọn ni wọ́n jìn sí i.
7Ọkàn mi dúró ṣinṣin, Ọlọrun,
ọkàn mi dúró ṣinṣin!
N óo kọrin, n óo sì máa yìn ọ́.
8Jí, ìwọ ọkàn mi!
Ẹ jí, ẹ̀yin ohun èlò orin, ati hapu,
èmi alára náà yóo jí ní òwúrọ̀ kutukutu.
9OLUWA, n óo máa fi ọpẹ́ fún ọ láàrin àwọn eniyan;
n óo sì máa kọrin ìyìn sí ọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.
10Nítorí pé ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tóbi, ó ga ju ọ̀run lọ,
òtítọ́ rẹ sì kan ojú ọ̀run.
11Gbé ara rẹ ga, Ọlọrun,
gbé ara rẹ ga ju ọ̀run lọ,
kí ògo rẹ sì tàn ká gbogbo ayé.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ORIN DAFIDI 57: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010